Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì ÌgbàlàÀpẹrẹ

Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì Ìgbàlà

Ọjọ́ 5 nínú 7

Títí àsìkò yí nínú Ẹ́kísódù, a ti rí bí Ọlọ́run ṣe fi agbára rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi Olùgbèjà àti Olùpèsè.

Àmọ́, ní Orí Òkè Sínáì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fihan wípé ìrìn àjò wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Nígbàtí Mósè wá lórí òkè tó ń gba òfin Ọlọ́run, Ísírẹ́lì di aláìnísùúrù. Torí náà, nínú ìdèkùn ọkàn ẹrú wọn, wọ́n yàn láti má a bọ òrìṣà tí wọ́n mọ, nkan tí ó farajọ àṣà àwọn ará Egypiti.

Ìbọ̀rìṣà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè yani lẹ́nu lẹ́yìn gbogbo ìrírí agbára Ọlọ́run tí wọ́n rí. Báwo ni wọn lè ṣe tètè kọ ẹ̀yìn sì Ọlọ́run bayi?

Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni wípé, gbogbo wa la ní irú ìwà yi. Nígbàtí Ọlọ́run ò bá tẹríba fún ìrètì àbàwọ́n wa, àwọn ààmì ìmúlẹ́rú wa sí ẹ̀ṣẹ̀ lè tún padà wá. Ipò ìṣòro - bíi ìpàdánù ìgbéga ni ibi iṣẹ́ àbí kí àwọn ẹlòmíràn rí ìfẹ́ ti ìwọ ó rí - àwọn ipò wọ̀nyí ru ojú tí a fi rí ìwà Ọlọ́run ò sì lè tán wá láti yan ìtẹ́lọ́rùn nínú ẹ̀ṣẹ̀.

Ìgbà mélòó lo ti rí ara à rẹ nínú ìdèkùn tí Ọlọ́run ti yọ ọ́ kúrò?

Nigbati àwọn àníyàn àti ẹ̀ṣẹ̀ bá mú wá pàdánù rírì ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, Ọlọ́run nípa oore ọ̀fẹ́ a má a rán wa leti ni gbogbo ìgbà.

Botilejepe kò tọ́ sì wá, Ọlọ́run fi ìfẹ́ ailabawọ́n, àánú àti ìdáríjì rẹ̀ wẹ̀ wá. Ọwọ yí kan náà tó lágbára láti gbéjà àti láti pèsè náà ló tútù ló sì ṣetán láti dárí jì.

A rí ọwọ́ yìí lẹ́nu ìṣe ni Ẹ́kísódù. Kódà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kọ ẹ̀yìn wọn síi, Ọlọ́run yàn láti dárí jì wọ́n.

Pelu bí àṣìṣe wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ṣe tó, Ọlọ́run ṣì nifẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì yan láti dì ìmùlẹ̀ ibasepọ̀ pelu wọn mú ṣinṣin.

Bíi òbí to ń wo ọmọ rẹ̀ tó ń kọ́ láti rìn, Ọlọ́run mọ̀ wípé a má a ṣubú. Àti bíi bàbà ìfẹ́ tó jẹ́, Ọlọ́run gbá wa mú nínú apá oore ọ̀fẹ́ rẹ..

Bayi, ǹjẹ́ oore oọ̀fẹ́ rẹ̀ gbà wa ní ààyè láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀? Rárá o! Ìdáríjì Ọlọ́run jẹ́ ìfìwépè wa sínú ayé òmìnira láti ọwọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀.

Ìdí nìyí tí Ọlọ́run fi fún àwọn ènìyàn rẹ ni àwọn òfin: láti dáábòbò wá lọ́wọ́ ìdánwò kí a bá a lè gbé ìgbésí ayé tó ní àmì ìrònú píwàdà.

Nípasẹ̀ Jésù a ń rìn pẹ̀lú Ọlọ́run tó ń dárí jì.

Ìríṣí:

Awon àṣìṣe wo ló dá ọ dúró láti sinmi nínú ìdáríjì Ọlọ́run?

Àdúrà:

Ọlọ́run, mo dúpẹ́ fún ìdáríjì àwọn àṣìṣe àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi. Jọ̀wọ́ tọ́mi sọ́nà nínú ayé titun tí Jésù gba fún mi kí èmi bá a lè bọ̀wọ̀ fún ọ nínú òun gbogbo ti mo bá sọ àbí ṣe. Àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì Ìgbàlà

Ní ìrírí bí ìtàn Ẹ́sódù ṣe lè tún ìrìnàjò rẹ ṣe lónìí. Eyi ti a mu láti inú ìwàásù Tyler Staton to pe ni “Ẹ́sọ́dù”, Ẹ̀kọ́ Bíbélì yí pè wá láti tẹ̀lé awon ọmọ Ísírẹ́lì bí wọn ṣe kúrò nínú ìmúlẹ́rú sì Ilẹ̀ Ìlérí, a sì ṣàsopọ̀ ńlá pẹ̀lú ayé Jésù àti ìṣe rẹ̀. Ṣàwárí bí ìlérí òmìnira Ọlọ́run àti àtúnṣe ṣe wà láàyè fún ọ.! Adúpẹ́ lọ́wọ́ LUMO, Tyler Station áti ìjọ Bridgetown tọ́n pèsè ètò yí. Láti wo ìwàásù Ẹ́sódù àti fún iwadi ẹ lọ sí https://bridgetown.church

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com