Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì ÌgbàlàÀpẹrẹ

Nínú Ẹ́kísódù, Ọlọ́run fi ara rẹ̀ hàn bíi Olùgbèjà, Olùpèsè, Olùdáríjì, àti Olùràpadà, to ń fi ọkàn rẹ̀ hàn nípasẹ̀ ipa kọ̀ọ̀kan. Àwọn ipa wọ̀nyí ṣọ̀kan nínú ìfarahán Rẹ̀, ìpilẹ̀ṣẹ̀ to dúró tó sì ń rán wa létí pé a kò dá kọjú sì ìdánwò.
Bí àwa ṣe ń gbé ní iwájú rẹ̀, a ó rí wípé Ọlọ́run ògo ni Ọlọ́run.
Ṣùgbọ́n kí ló túmọ̀ sí gangan? Ọ̀rọ̀ tó júwe ògo ni Hébérù ni kavodi - tó jẹ́ àkópọ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣàlàyé ìwúwo, títóbi, àti agbára Ọlọ́run.
Ronú nípa òkun - bí ìrú omi na a ṣe tó àti agbára tó ń rú ìjìnlẹ̀ ẹ rẹ̀. Èyí jẹ́ bíntín nínú kavodi Ọlọ́run, ògo Rẹ̀, tó ń koja nínú òkè àti ìsàlẹ̀ ojojúmọ́ ayé è rẹ. Kìí ṣe inú igbó tó ń jó àbí inú àrá orí òkè ńlá nìkan láti rí i, sugbon a rí i nígbàkan náà nínú ohùn ìfẹ́ rẹ̀ tútù nígbàtí ó nílò rẹ jùlọ.
Mósè tìkalárarẹ̀bá kavodi Ọlọ́run pàdé nínú Ẹ́kísódù. Bótilẹ̀jẹ́pẹ́ kò rí Ọlọ́run lójú korojú, ìmọ́lẹ́ bo Mósè nípasẹ́ ògo Ọlọ́run tó bá pàdé - tó bẹ́ ẹ̀ gẹ́ tó ní láti bo ojú ara rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ.
Ìrírí yí kìí ṣe fún Mósè nìkan. Ìtàn Ẹ́kísódù wà, lọ́nà tímọ́tímọ́, fún àwọn tí wọn ní ìrírí náà tààrà. Ṣùgbọ́n ó tún wà fún àwa náà tí a wà nínú Jésù.
Jésù fi hàn pé ògo Ọlọ́run kìí ṣe fún lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí nìkan, ṣùgbọ́n a lè ríi ó sì wúwo pẹ̀lú. Ó yí wa ká lójoojúmọ́ ayé wa, ó sì ń pè wá láti ni ìrírí ìjìnlè àti àyípadà agbára rẹ níbi tí a wà. Ọlọ́run yìí - Ọlọ́run tó kún fún ògo - òun lo ńpé wá láti ni ìrírí iwájú rẹ àti òmìnira nínú ìrìn àjò Ẹ́kísódù wá.
Nínú fíìmù LUMO wòlíì Esra kà láti inú Diutarónómì, “...ìyè àti ikú là gbé sì iwájú yín.” Ògo Ọlọ́run kò kọjá àfọwọ́bà rẹ.
A lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run tó ń gbèjà, tó ń gbàlà, tó ń pèsè, to sì ń dáríjì. A lé wá kavodi Ọlọ́run rí, ká sì rántí pé Ọlọ́run kan náà tó dá sí ti Ísírẹ́lì yóò dá sì ti wá lèní.
Ìríṣí:
Nípasẹ̀ Kristi, Ọlọ́rungbà ọ́ là lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kí ìwọ bá a lè gbé nínú ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀. Ká 2 Kọ́ríńtì 3:7-18 kò ó sì ṣe àṣàrò lórí ntí ó lè túmọ̀sí láti gbé nínú ọ̀tun, ọ̀nà tó ní ògo tí Ọlọ́run ṣí sílẹ̀ fún ẹ.
- Kí lo ni lati se léni láti yan iye tí Ọlọ́run pèsè fún ẹ.?
- Ṣe ò ń gbé nínú ìgboyà gidi nítorí nkan ti Jésù ti ṣe fún ẹ (2 Kọ́ríńtì 3:12)? Bí bẹ̀ẹ̀ kọ́, kí ló ń dá ọ dúró?
Àdúrà:
Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ìgbèjà, ìràpadà, ìpèsè, àti ìdáríjì tó ó fun mí. Rán mí lọ́wọ́ láti kọ́ bí a ti ń gbára lé ògo rẹ nígbà gbogbo. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ní ìrírí bí ìtàn Ẹ́sódù ṣe lè tún ìrìnàjò rẹ ṣe lónìí. Eyi ti a mu láti inú ìwàásù Tyler Staton to pe ni “Ẹ́sọ́dù”, Ẹ̀kọ́ Bíbélì yí pè wá láti tẹ̀lé awon ọmọ Ísírẹ́lì bí wọn ṣe kúrò nínú ìmúlẹ́rú sì Ilẹ̀ Ìlérí, a sì ṣàsopọ̀ ńlá pẹ̀lú ayé Jésù àti ìṣe rẹ̀. Ṣàwárí bí ìlérí òmìnira Ọlọ́run àti àtúnṣe ṣe wà láàyè fún ọ.! Adúpẹ́ lọ́wọ́ LUMO, Tyler Station áti ìjọ Bridgetown tọ́n pèsè ètò yí. Láti wo ìwàásù Ẹ́sódù àti fún iwadi ẹ lọ sí https://bridgetown.church
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com