Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì ÌgbàlàÀpẹrẹ

Northrop Frye nígbàkan ló sọ wípé Ẹ́kísódù jẹ́ “òun kan ṣoṣo tó ń ṣẹlẹ̀ nínú Bíbélì.” Kìí ṣe nípa Ọlọ́run àti Mósè nìkan; ó wà nípa wa. Ó wà nípa bí a ṣe ń ké jade nínú ìrora wa pàápàá lónìí, ó wà nípa ọ̀nà ti a n gba sá tẹ́lẹ̀ ìrètí èké, àti ọ̀nà ti Ọlọrun gbà wọnú ayé wa láti fún wa ní àwọn ǹkan síwájú si.
Òmìnira yìí wà fún gbogbo àwọn tó bá wù láti gbà á, sugbon o bá iye wá.
Fún Ísírẹ́lì, wọn ní láti rúbọ ọ̀dọ́ àgùntàn kí ìdílé wọn báà lè ní ìdáábòbò lọ́wọ́ ìbínú tí Ọlọ́run dà sí orí àwọn akẹ́tú wọn. Ọjọ́ yìí - tí a wá mọ̀ sí Ìrékọjá - yóò di àjọ̀dún ìrántí Ẹ́kísódù.
Fún àwa, a ní láti ṣe ẹbọ tó tóbi jù - èyí tó má a bo ẹ̀ṣẹ̀ wá tí yóò sí já á ìdè lẹ́ẹ̀kan àti fún gbogbo ìgbà. Ẹni tí Jésù jẹ́ nìyẹn. Ọlọ́run nìyẹn: Olùràpadà wá - Ẹni tó mu wá padà láti ibi tí ẹ̀ṣẹ̀ há wa sí sínú ọwọ́ ìfẹ́ rẹ̀.
Wo ìwòye àkókò náà lórí àgbélébùú. Jésù, àgùntàn pípé ti Ọlọ́run, tó ń jìyà torí kí a báa lè gbé ẹrù àjàgà rẹ kúrò.
Ìfẹ́ rẹ̀ fún ọ kii se ní ti ọ̀rọ̀ nìkan; ó dà á pẹ̀lú gbogbo ẹ̀jẹ̀ rẹ to tá sílẹ̀.
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, ọkàn rẹ̀ tún jí.
Èyí ni ibi gíga orin Ẹ́kísódù tó kárí i gbogbo Bíbélì pátá. Láti ìbẹ̀ẹrẹ̀ orin yìí, ìṣẹ̀dá yí padà títí láì.
Nígbàtí òkunkún bíríbírí bá de, tí ìfòyà gbá ọkàn wa mú, àbí tí àṣìṣe àti ẹ̀rí ọkàn bò wá lójú, rántí pé Jésù ni Olùràpadà rẹ - ẹni tí kò mọ àníyàn rẹ nìkan ṣùgbọ́n tó ti borí rẹ fún ọ.
Nípasẹ̀ Jésù, àti Jésù nìkan, ìyípo ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtìjú ti wó. Nínú àgùntàn Ọlọ́run, ó ní ìgbàlà.
Ìríṣí:
Bawo ni ayé ẹ ó bá ṣe rí tí ó bá gbagbọ ni tòótọ́ pé ìwọ kìí ṣe ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ̀?
Adura:
Jésù, ìgbàlà ó tọ̀ sí mi, sugbon o ṣì kú fún mi. Mo dúpẹ́ pé ó ní ìfẹ́ mi ó sì rà mí padà nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ. Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí

Ní ìrírí bí ìtàn Ẹ́sódù ṣe lè tún ìrìnàjò rẹ ṣe lónìí. Eyi ti a mu láti inú ìwàásù Tyler Staton to pe ni “Ẹ́sọ́dù”, Ẹ̀kọ́ Bíbélì yí pè wá láti tẹ̀lé awon ọmọ Ísírẹ́lì bí wọn ṣe kúrò nínú ìmúlẹ́rú sì Ilẹ̀ Ìlérí, a sì ṣàsopọ̀ ńlá pẹ̀lú ayé Jésù àti ìṣe rẹ̀. Ṣàwárí bí ìlérí òmìnira Ọlọ́run àti àtúnṣe ṣe wà láàyè fún ọ.! Adúpẹ́ lọ́wọ́ LUMO, Tyler Station áti ìjọ Bridgetown tọ́n pèsè ètò yí. Láti wo ìwàásù Ẹ́sódù àti fún iwadi ẹ lọ sí https://bridgetown.church
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com