Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì ÌgbàlàÀpẹrẹ

Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì Ìgbàlà

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ní etí òkun pupa, Ọlọ́run ò pèsè ọ̀nà láti là òkun kọjá nìkan, ó tún pèsè àwòrán òun ti Jésù yóò padà dì. Ati há sínú ẹ̀ṣẹ̀ wá, torí na Ó di ọ̀nà kan ṣoṣo - ilẹ̀ gbígbẹ fún wa láti rìn nínú ìrìn àjò wá padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Nínú Ẹ́kísódù, Ọlọ́run fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi Olùpèsè, Ẹni tó ń fún wa ní ohun tí a kò lè fún ra wá.

Nínú fídíò yí, wò bí Ọlọ́run ṣe lànà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú ìṣòro tó le. Nígbàtí wọn ró wípé kò sọ́nà àbáyọ, Ọlọ́run lànà fún wọn .

Lọ́nà kan náà lónìí, Ọlọ́run un pèsè ìtúsílẹ̀ ti ọpọlọ, ìmọ̀lára, ara, ati ẹ̀mí fún wa; Jésù fi hàn wá nígbà ayé rẹ̀ láyé yìí pé òun ṣẹ̀kẹ́ wa. Nínú Mateu 14, nigbati tí ó rí ojú ẹgbẹ̀rún àwọn ọmọlẹ́hìn rẹ̀ tí ebi ń pa, Jésù sọ oúnjẹ ọmọdé kùnrin kan di ìlọ́po fún wọn láti jẹ.

A kò mọ èsì í wọn dájú, sugbon a lè rò bóyá ìpèsè ìyanu tí Jésù ṣe yìí rán ogunlọ́gọ̀ wọn létí àwọn ìtàn Ẹ́kísódù tí wọn gbọ́ ni kékeré - àwọn ìtàn nípa bí Ọlọ́run ṣe gbọ́ ẹkùn ebi àwọn baba wọn nínú aginjù, tó sì pèsè oúnjẹ ọjọ́ ti mánà ati àparò fún wọn.

Bí a ṣe ń rí àpẹrẹ ìtàn Ẹ́kísódù tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìwé mímọ́ yẹ kó mú wá rí àwọn àlàfo nínú ayé wa tí a ti nílò Olùpèsè. Ẹ̀là nínú ètò ìsúná, àwọn ìṣètò tó kọjá àfaradà, àyẹ̀wò ìlera tó kọ mí lóminú, àwọn ìṣòro wọ̀n yí tan ìmọ́lẹ̀ sì àìlágbára wa láti ṣe oun gbogbo.

Ohunkóhun tí ìbá à dínkù láyé rẹ, o lè mú wọn wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run kí ó sì gbagbọ wípé òun ṣì ni Ọlọ́run tó ń pèsè fún àwọn ọmọ rẹ̀.- fún wa. Òun ṣì ní Ọlọ́run tó ń bá wa dá síí ọ̀rọ̀ nípò wa.

“‘Kí la má jẹ? Kí la má mu? Kí la má wọ̀?’ Àwọn èrò tó ń jọba lọ́kàn àwọn alaigbagbọ ni wọn yí, ṣùgbọ́n bàbà rẹ tí ń bẹ lọ́run tí mọ gbogbo òun ti o nílò. Wà ijoba Ọlọ́run ṣáájú òun gbogbo, sì má a gbé ìgbé ayé òtítọ́, yóò sì fún ọ ní òun gbogbo tí ìwọ nílò.”

Nítorínáà, létí “Òkun Pupa” rẹ, láàrin awọn àìtó rẹ, mọ̀ wípé Ọlọ́run ṣe tán ó sì wá fún ọ láti pè. Ó lè má jẹ́ẹ̀ lọ́nà tí o rò, sugbon nípasẹ̀ Olùpèsè ńlá, ìwọ yóò rìn omi náà ti yóò pín yà.

Ìríṣí:

Ní ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà àbáyọ fún ọ nígbàtí kò sí ọ̀nà míràn?

Adura:

Ọlọ́run, ìwọ ni Olùpèsè ńlá mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé ọ ní gbogbo abala ayéè mi. Àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì Ìgbàlà

Ní ìrírí bí ìtàn Ẹ́sódù ṣe lè tún ìrìnàjò rẹ ṣe lónìí. Eyi ti a mu láti inú ìwàásù Tyler Staton to pe ni “Ẹ́sọ́dù”, Ẹ̀kọ́ Bíbélì yí pè wá láti tẹ̀lé awon ọmọ Ísírẹ́lì bí wọn ṣe kúrò nínú ìmúlẹ́rú sì Ilẹ̀ Ìlérí, a sì ṣàsopọ̀ ńlá pẹ̀lú ayé Jésù àti ìṣe rẹ̀. Ṣàwárí bí ìlérí òmìnira Ọlọ́run àti àtúnṣe ṣe wà láàyè fún ọ.! Adúpẹ́ lọ́wọ́ LUMO, Tyler Station áti ìjọ Bridgetown tọ́n pèsè ètò yí. Láti wo ìwàásù Ẹ́sódù àti fún iwadi ẹ lọ sí https://bridgetown.church

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com