Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì ÌgbàlàÀpẹrẹ

Ronú nípa ìgbà kan tí ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá ẹ - bóyá nígbà ìdààmú àìsàn, ìpọ́njú àìlówó lọ́wọ́, àbí ìsòro ìbáṣepọ̀. Ní àkókò bá wọ̀nyí, nígbàtí gbogbo ǹkan jọ pé ó dojú rú, a má ń pòngbẹ fún ẹnìkan tó lè gbèjà wa.
Nínú Ẹ́kísódù, a ṣe àwárí Ọlọ́run tó ń gbèjà àwọn tí wọn ò lè gbèjà ara wọn- Ọlọ́run tó ń gbọ́ àti Ọlọ́run tó ń ṣè ìtọ́jú.
Bí a ṣe ríi ni Ẹ́kísódù 3, Ọlọ́run dáhùn si ìjìyà àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa yíyan Mósè gẹ́gẹ́ bíi ohun èlò fun ìtúsílẹ̀ wọn. Dídúró níwájú Fáráò, alágbára jùlọ ní gbogbo ayé, Mósè pàṣẹ kí wọn tú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀.
Èsì Ọlọ́run - àjàkálẹ̀ aàrùn mẹ́wàá - jẹ́ ìfihàn ńlá agbára Rẹ̀.
Àwọn àjàkálẹ̀ aàrùn wọ̀nyí ò kàn láti fipá mú Fáráò nìkan, wọ́n jẹ́ ìkéde àṣẹ Ọlọ́run lórí i gbogbo ìsẹ̀dá àti ìlérí rẹ tí kò le yípadà láti gbéjà àwọn ènìyàn rẹ̀.
Nígbàkúùgbà nínú Bíbélì, a ń rí ìtàn yí léraléra. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run há sínú ẹ̀ṣẹ̀, Ọlọ́run sì ń tú wọn sílẹ̀. Ju gbogbo ẹ lọ, ìtàn náà parí nígbàtí Ọlọ́run fara hàn bíi ènìyàn: nínú ẹni Jésù.
“Ọlọ́run rán ọmọ rẹ nínú ara bíi èyí tí àwa ẹlẹ́ṣẹ̀… ó sì pàṣẹ òpin fún ẹ̀ṣẹ̀ lórí wa nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ tó fún wa gẹ́gẹ́ bíi ẹbọ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (Romu 8:3)
Nítorí ìfẹ́ tí o ń tari ẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò lè ní òye rẹ̀ tán, Jésù fi takuntakun gbéjà àwọn tí ó ní olùgbéjá. Nínú ìbínú Mímọ́, ó ti àwọn tábìlì ṣubú nínú tẹ́ńpìlì ó sì sọ́rọ́ ní ipò àwọn tí kò lóhùn. Ó dojú kọ ẹ̀ṣẹ̀ wa ó sì pàṣẹ òmìnira fún wa pẹ̀lú ẹbọ rẹ̀ lórí àgbélébùú.
Lẹ́hìn náà, nínú agbára ńlá ẹ̀, Jésù dìde kúrò nínú òkú ó sì borí àwọn agbára tó ń wá láti yà wá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Nínú Orin Dáfídì 23 Ọlọ́run kan náà tí ń gbéjà là rí nínú àwòrán olùṣọ́ àgùntàn. Ẹsẹ Kẹrin sọ pé, “Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi.”
Ṣàkíyèsí, Ìgbani sílẹ̀ Ọlọ́run kìí ṣe mímú kúrò nínú àfonífojì, ṣugbon ó jẹ́ ìbùkún nínú ẹ̀ níbẹ̀. Ó jẹ́ ìbùkún àfihàn Ọlọ́run tó ń rìn ìrìn àjò pẹ̀lú wa.
Bí Ọlọ́run ò bá kàn mú ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú ọ wà láìlágbára kúrò, ó lè gbẹ́kẹ̀ lé pé nítorí ó fẹ́ràn ẹ, yóò pa ọ́ mọ́ yóò sì gbéjà rẹ bí ó ṣe ń tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò Ẹ́kísódù rẹ.
Ìríṣí:
Àwọn ìkọ̀sẹ̀ wo ló ń dójú kọ ọ́? Bí ó ṣe ń bá ojo ẹ lọ, ronú lórí Orin Dáfídì 23 kí ó sì jẹ kó jẹ́ àdúrà rẹ sì Ọlọ́run tó ń gbéjà rẹ.
Àdúrà:
Ọlọ́run, Ìwọ ni Olùgbèjà mi. Ràn mí lọ́wọ́ kí n má fì sínú ìfòyà. Mo mọ̀ pé ìwọ́ wá pẹ̀lú mi nígbà gbogbo. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ní ìrírí bí ìtàn Ẹ́sódù ṣe lè tún ìrìnàjò rẹ ṣe lónìí. Eyi ti a mu láti inú ìwàásù Tyler Staton to pe ni “Ẹ́sọ́dù”, Ẹ̀kọ́ Bíbélì yí pè wá láti tẹ̀lé awon ọmọ Ísírẹ́lì bí wọn ṣe kúrò nínú ìmúlẹ́rú sì Ilẹ̀ Ìlérí, a sì ṣàsopọ̀ ńlá pẹ̀lú ayé Jésù àti ìṣe rẹ̀. Ṣàwárí bí ìlérí òmìnira Ọlọ́run àti àtúnṣe ṣe wà láàyè fún ọ.! Adúpẹ́ lọ́wọ́ LUMO, Tyler Station áti ìjọ Bridgetown tọ́n pèsè ètò yí. Láti wo ìwàásù Ẹ́sódù àti fún iwadi ẹ lọ sí https://bridgetown.church
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com