Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

All Who Are Weary: God Is With Me

Ọjọ́ 8 nínú 8

Ọlọ́run wa pẹlú Mí ní Àfonífojì

Olúwa ní olùṣọ-àgùtàn mí, èmi ki yíò ṣe alàiní,
Ó mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá oko tútù,
ó mú mí lọ sí iha omi didakẹ rọ́rọ́,
ó tu ọkàn mi lára.
‭ o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo
nitori orukọ rẹ̀. Bi mo tilẹ̀ nrìn
láàrin àfonífojì,
èmi kì yíò bẹ̀ru íbi kán,
nítorí ti Iwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá rẹ,
wọ́n tù mí nínú. — Sáàmù 23:1-4

Ìlérí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi ní àfonífojì.

Àfonífojì wo ni o tí bá ara rẹ? Níbo ní àwọn òjìji ti yọjú? Olùṣọ́ Àgùntàn rere rẹ ń bá ọ rìn, ó ń tọ́ ọ sọ́nà sí àwọn ibi ìsinmi, ó ń ṣe ìrọ́pò ohun tí ó ti sọnù, ó sì ń ṣọ́ ọ pẹ̀lú àkíyèsí taápọntaápọn. Awọn ọna Rẹ ati ọkan Rẹ ni itunu ni àrin ìrúkèrúdò, àti wípé o lè máa rìn láàrin ìjàkadì nítorí tí O di alábàárìn rẹ.

Ìjọsìn nínú Ìrètí:

Orín Dáfídì 23 láti ọwọ́ Karissa Frampton

Gbìyànjú èyí: Máà ṣe àkọsílẹ̀

Fa ìwé-àkọsílẹ̀ túntún jáde tàbí èyí tí ó ti gbó. Múu lọ sí ìta tàbí kí o fi ìdí lélẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ fèrèsé tí ó mọ́lẹ, ní ibikíbi tí ó dákẹ́, tí ó dùn ún wò pẹlu imọlẹ ojú ọjọ́. Yọ ìdėri ní orí ikọwe ki o sí kọ èrò ọkàn rẹ sí orí ìwé. Pín àwọn èrò rẹ, ìbẹrù rẹ, ìrètí rẹ. Ṣeé ní ti ara rẹ́, bá Jésù sọ gẹ́gẹ́bí ẹ̀dùn ọkàn rẹ. Jẹ́ kí O mọ̀ bí o tí ṣe mu ọ́ ní omi tó rẹ kí o sì béèrè pé kí O pàdé rẹ níbẹ.

Nípa Ìpèsè yìí

All Who Are Weary: God Is With Me

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Sarah Freymuth / Awake Our Hearts fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ sii, ṣe àbẹ̀wò sí: https://sarahfreymuth.com/