Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

A Dá Mi Ní Pẹ̀lẹ́, A Sì Ti Rí Mi
Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀,
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
Ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé;
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí ní ọjọ́ tí a dá wọn
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí. -Saamu 139:15-16
Ìlérí Náà: A ṣe mi ní pẹ̀lẹ́, a sì rí mi.
A ti dá ọ pẹ̀lú ète. Àníyàn ṣíṣe tabi kí ó fẹ́ mọ gbogbo ìgbésẹ̀ ètò náà kí ó tó ṣe é. A dá ọ pẹ̀lú ète tó dára, Ọlọ́run kò sì ṣe àṣìṣe nígbà tí ó so ọ di odidi. Ọlọ́run yìí tí ó dá ọ ní pẹ̀lẹ́ ó mọ̀ é tímọ́tímọ́. A lè fọkàn tán an pé yóò bójú tó ẹ.
Ìjọsìn Láàárín Àkókò Ìdúródeni:
Enclosed by You by Josh Garrels
Gbìyànjú Èyí Wò: Jẹ́ Onímọ̀ Iṣẹ́ ọnà
Gbìyànjú láti yàwòrán ohun tó wà níwájú rẹ. Ó lè jẹ́ àwọn ìwé tó wà lórí tábìlì ìjókòó rẹ tàbí àwọn ìrọ̀rí tó wà lórí ibùsùn rẹ. Ó lè jẹ́ ọgbà tó wà níta fèrèsé rẹ tàbí ẹni tí ó fẹ́ràn tí ó ń jókòó sí órí ìjókòó. Gbé ewé ìwé kan, pẹ́ńsù tàbí pẹ́ńsù aláwọ̀ tó máa mú kí ìwé náà túbọ̀ lẹ́wà sí i. Bẹ̀rẹ̀ sí ní yàwòrán; kò ṣe pàtàkì bí ó ṣe rí; jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa lọ káàkiri ojú ewé.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.
More