Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

Ọlọ́run wà pẹ̀lú ù mi
“Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.” Matiu 11:28-30
Nígbàtí a bá rò ó wípé àwọn èniyàn ti gbàgbé wa tàbí tí a dá wà, ó burú. Wíwà ní ipò ṣíṣẹ àníyàn burú fún ararẹ̀, tí a bá tún wá rò ó wípé ǹjé ẹni kankan rí wa nítòótọ́ bí a ṣe wà tàbí ṣé wón ṣetán láti wo ipò tí a wà yì láti ṣe ìrànlọ́wọ́, èyí á tún dákún àníyàn tí ó wà nílẹ̀
Ẹ̀ru dídá wà yì tí à ńrò, bí ó ṣe ńjẹ́ kí ara wa gbọ̀n, àti àwọn ìbéèrè nínú ẹ̀mí á máa jẹ́ kí á wò rá rà rá fún Ọlọ́run nígbàtí gbogbo ǹkan ò bá lọ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n lọ. Níbo ni Ó wà nígbàtí ẹ̀rù ńbà wá tí ó dàbí wípé ẹ̀rù yí fẹ́ borí? Nígbàtí gbogbo èrò yí ń kọjá lọ ní ọkàn wa? Nígbàtí a bá ń rò wípé ṣé bí ìbẹ̀rù yí ó ṣe di ohun tí a ó máa bá yí ní gbogbo ìgbà?
A fẹ́ ìfọkànbalẹ̀ wípé Ọlọ́run ń rí wa nínú àwọn ohun tí à ń là kọjá àti láti mọ̀ wípé ó gbọ́ igbe wa fún ìrànlọ́wọ́
Àti Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́, ṣe ìlérí láti wà pẹ̀lú u wa. Àní nígbàtí ó bá dàbí wípé Ó jìnà sí wa, ojú u Rẹ̀ kò fi ìgbà kankan kúrò níbi tí a wà, Ó ṣì ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn
Ṣe Ìrántí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú ù mi.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.
More