Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

All Who Are Weary: God Is With Me

Ọjọ́ 2 nínú 8

Òun Yíó Ró Mi Ní Agbára Yíó Sì Rán Mì Lọ́wọ́

Ìwọ má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ;
má fòyà nítorí Èmi ni Ọlọ́run rẹ.
Èmi yíó fún ọ ní okun nítòótọ́, Èmi yíó ràn ọ́ lọ́wọ́;
nítòótọ́, Èmi yíó fi ọwọ́ ọ̀tun òdodo mi gbé ọ sókè. -Àìsáyà 41:10

Ìlérí Náà: Òun yíó fún mi ní okun yíó sì ràn mí lọ́wọ́.

Agbára káká ní ènìyàn fi ń jí ní òwúrọ̀ kí ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n nígbàtí ó jẹ́ pé àárẹ̀ tí mú u. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń fún ọ ní okun. Ó ń gbé ọ ró nígbàtí ò ń ṣ'àárẹ̀, Òun ní òkúta ìtìsẹ̀ rẹ nígbàtí ẹsẹ̀ ré ń yọ̀, Òun sì dì ọ́ mú pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo Rẹ̀. Ó ṣe ìlérí pé Òun yíó fún ọ ní okun tí o níílò lónìí, Ó sì mú dá ọ lójú pé Òun ni Ọlọ́run rẹ nítòótọ́.

Ìjọ́sìn nínú Ìrètí:

Not Even Once (Kìí Tilẹ̀ se Ẹ̀ẹ̀kan) láti ọwọ́ Benjamin William Hastings

Gbìyànjú èyí: Àsìkò Tíì

Ló àsìkò díẹ̀ láti po ife tíì kan. Yan irúfẹ́ èyí tí ń tu ni lára, bí í spearmint, lavender, or chamomile. Jẹ́ kí àgé omi rẹ gbóná, kí o rọra dàá jẹ́ẹ́jẹ́ tí omi bá ti hó. Wo bí omi àti àwọn ewé tíì ṣe jọ pàdé tí wọ́n sì kún inú ife. Wo bí ooru gbígbóná ṣe ń lọ́ bìrìpó, bí ó bá wáá ti t'oró tán, ti ko gbóná ju, ṣẹ́ diẹ mu. Gbádùn rẹ̀.

Nípa Ìpèsè yìí

All Who Are Weary: God Is With Me

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Sarah Freymuth / Awake Our Hearts fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ sii, ṣe àbẹ̀wò sí: https://sarahfreymuth.com/