Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

OLÚWA wà pẹ̀lú Mi ní Ibi Gbogbo Tí Mo Bá Lọ
“Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.” -Jóṣúà 1:9
Ìlérí Náà: Olúwa wà pẹ̀lú mi ní ibikíbi tí mo bá lọ.
Kòsí òjìji tàbí agbègbè òkùnkùn kan tí Olúwa kò ní tẹ̀lé ọ lọ. Bíi ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo òkùnkùn ti rí sí I, àti wípé Òun ló ba lórí ohun gbogbo tí ń gbìyànjú láti fà ọ́ sẹ́yìn. Má ṣe bẹ̀rù. OLÚWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ohunkóhun yòówù tí o lè máa là kọjá. Ó ká ojú òṣùwọ̀n tayọ Ó sìí ń fẹ́ láti bá ọ pàdé nínú ìbànújẹ́, ìfòyà, àti ìrẹ̀wẹ̀sì rẹ. Kódà, Ó fẹ́ bá ọ pàdé níbi kọ́lọ́fín tí o wà kí o ba lè gbé ara lé E.
Ìjọ́sìn nínú Ìrètí:
I Am Not Alone (Nkò Dá Níkan Wà) láti ọwọ́ Kari Jobe
Gbìyànjú èyí: Oúnjẹ Òwúrọ̀ fún Àṣálẹ̀
Yí ì padà kí o se oúnjẹ òwúrọ̀ ní àṣálẹ̀. Ìtùnú jíjẹ oúnjẹ òwúrọ̀ ní àṣálẹ́ lè mú inú àti ọkàn ènìyàn balẹ̀ dẹ̀ẹ̀. Dín ẹyin, se ẹran, kí o sì kún ilé ìdáná pẹ̀lú òórùn aládìńdùn. Fi bota pa búrẹ́dì, da omi-ọsàn tútù sínú ife, kí o wà jókòó láti jẹ ìgbádùn. Tọ́ ọ wò, jẹ ìgbádùn ekìrí kààǹkan, kí o sì wá dúpẹ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.
More