Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

All Who Are Weary: God Is With Me

Ọjọ́ 7 nínú 8

Jésù Fi Ọ́kàn Ẹ̀rù Mí Balẹ̀

‭Ṣùgbọ́n lójúkannáà ni Jésù wí fún wọn pé, "Ẹ tújúká; Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù." — Mátíù 14:27

Ìlérí náà: Jésù mu mí l'ọ́kan balẹ̀.

Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ṣe ń lọ lórí ìjí omi òkun, òjò ìṣòro lè rọ̀ sí oókàn-àyà àti èrò-inú rẹ. Ṣùgbọ́n mú ọkàn le! Ní àárín ìkuukùu àti ìrúmi òkun, Jésù la ààrin wọ́n kọjá láti dé ọ̀dọ̀ rẹ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Ó sì mu dá ọ lójú wípé Òun ń bọ̀; Ó wà ní ibí. Nígbàtí a bá sọ ẹ̀rù ọkàn wa fún Ùn, yíò yára wọlé pẹ̀lú ìdẹ́rùn àti okun. Mú ọkàn le; Jésù wa nìbi.

Ìjọ́sìn nínú Ìrètí:

You’re Gonna Be OK láti ọwọ́ Jenn Johnson

Gbìyànjú èyí: Orin Ojú-agbo

Lọ sí ibikán kí o lọ tẹ́tí sí orín ojú-agbo, orín àpèjọ kan, orín ni ile oúnjẹ kan, orin ìsìn nínú ìjọ. Jẹ́ kí àwọn ìró ohún èlò ọrin náà ràgà bo ọ́, jẹ́ kí ohùn àwọn akọrin pàdé rẹ, kí o sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà tọ̀ ọ́ lára já. Nkánkàn wa nínú pípéjọ pọ̀ pẹ̀lù àwọn ẹlòmíràn lati tẹ́tí sí àwọn olórin tí ó m'ọ́yán lórí, tíí máa mú ni lọ sí ìbi ìdákẹ́jẹ́, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, orín táà nkọ lọ́wọ́lọ́wọ́ yí yíó wáá jẹ́ ìrírí ẹ̀mí bí o ṣe ń kókìkí ẹwà ohùn tí Ọlọrun dá

Nípa Ìpèsè yìí

All Who Are Weary: God Is With Me

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Sarah Freymuth / Awake Our Hearts fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ sii, ṣe àbẹ̀wò sí: https://sarahfreymuth.com/