Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

Ọlọ́run Àlàáfíà Náà Wà Pẹ̀lú Mi
Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín. -Róòmù 15:33
Ìlérí Náà: Ọlọ́run àlàáfíà náà wà pẹ̀lú mi.
Ọlọ́run àlàáfíà, ìtura, ìdẹrùn, àti gbogbo ohun dídára súnmọ́ ọ. Ó wà ní ìtòsí. O lè mí kanlẹ̀ pẹ̀lú ìsinmi nínú òtítọ́ wípé Ọlọ́run àlàáfíà yí ń ṣẹ́ ọwọ́ sí ọ àti wípé Ó ń fi àlàáfíà yí lọ ọkàn, ara àti ẹ̀mí rẹ. Tẹ́ ọwọ́ gba ohun tí Ó ṣe tán láti fi fún ọ. Sinmi nínú wíwà ní ìtòsí Rẹ̀, nínú ìtọ́jú Rẹ̀, àti nínú àlàáfíà Rẹ̀ tí ń wo'ni sàn.
Ìjọsìn Ní Ibi Ìdúró:
Àwọn Ǹkan Dídára láti ẹnu SEU Worship
Dán Èyí Wò: Tan Àbẹ́là Kan
Ra àbẹ́là titun tàbí kí o tú ilé fún àjókù àbẹ́là tí o ti gbàgbé sí ìsàlẹ̀ àpótí. Mú igi ìṣáná nínú pálí, ṣá a, kí o sì wo bí igi náà ti mú iná. Jẹ́ kí igi náà jó fún ìṣẹ́jú-àáyá kan, ṣe àkíyèsí iná rẹ̀, kí o sì gbe sún mọ́ òwú àbẹ́là náà kí o wá wo bí ó ti mú iná. Jẹ́ kí òórùn tí ó tẹ̀lé gba yàrá náà àti imú rẹ kan, àti iná àbẹ́là náà bí ó ti ń jó.
Nípa Ìpèsè yìí

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.
More