Gbogbo Àwọn Tí Ó Ṣàárẹ̀: Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú MiÀpẹrẹ

All Who Are Weary: God Is With Me

Ọjọ́ 3 nínú 8

Jésù wà Pẹ̀lú Mi ní Igbà Gbogbo

"... kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo, títí ó fi dé òpin ayé." Mátíù 28:20

Ìlérí Náà: Jésù wà pẹ̀lú mi ní ìgbà gbogbo.

Jésù ṣe ìlérí wíwà pẹ̀lú wa títí dé òpin ayé. Kì í ṣe pé yíò gba ìsinmi fún ìwọ̀n ọdún díẹ̀ tàbí kí Ó yẹra fún sáà kan. Ó yọ̀nda ara Rẹ̀ pátápátá fún ọ, kò sì níi d'ẹ́kun àti ní ìfẹ́ rẹ, àti láti wà pẹ̀lú rẹ ní ìgbà tí o bá ń bẹ̀rù tàbí tí kò si ìdánilójú fún ọ. Ní ìgbà tí Jésù bá sọ fún ọ ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, "Mo wà pẹ̀lú rẹ ní ìgbà gbogbo", Ó dúró ti ohun tí Ó sọ.

Ìjọ́sìn Nínú Ìdúró:

Kristi Olúwa wà Pẹ̀lú Mi l'áti ọwọ́ Stephany Gretzinger

Gbìyànjú eléyìí: Bọ́ sí ìta

Jókòó ní ìta. Ní ibi tí ó dákẹ́ rọ́rọ́. Bóyá ó lè gbúró àwọn ẹyẹ tàbí bí afẹ́fẹ́ ṣe ń fẹ́. Ṣe àkiyèṣí àwọn orin ìṣẹ̀dá, kí ó sì ní ìmọ̀lára àtẹ̀gùn tí ó ń fẹ́ lù ọ. Wó bí àwọn ẹ̀ka igi ṣe ń mí síwá-sẹ́hín tí wọ́n sì tẹ̀lé ibi tí ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ ń da'ríi wọn sí. Àwọn ìró wọ̀nyí lè mú kí àyà àti ọkàn rẹ balẹ̀ láì jẹ́ wí pé o gbé ìgbésẹ̀ kan.

Nípa Ìpèsè yìí

All Who Are Weary: God Is With Me

Èyí ni ọ̀sẹ̀ kínní nínú ètò olọ́sẹ̀ méje tí ó mú ọ rin àwọn ìjàkadì ti àìbàlẹ̀ ọkàn já bí oó ṣe máa di òtítọ́ Bíbélì àti àwọn ìlérí Ọlọ́run mú. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ yìí ń pèsè ìṣírí àti ìgbéṣẹ́ tí ó yanrantí láti mú ọkàn àti èrò inú rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jésù ní àárín àníyàn. Ìlérí ọ̀sẹ̀ yìí: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Sarah Freymuth / Awake Our Hearts fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ sii, ṣe àbẹ̀wò sí: https://sarahfreymuth.com/