Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

Síbẹ̀, Ẹ Máa Yọ̀
Alábukúnfún ni àwọn tí a ńṣe inúnibíni sí nítorí òdodo: nítorí tíwọn ni ìjọba ọ̀run. Alábukúnfún ni ẹ̀yin ní ìgbà tí àwọn ẹlòmíràn bá n gàn yín, tí wọn ń ṣe inúnibíni síi yín, tí wọ́n sì n sọ onírúurú ọ̀rọ̀ èké búburú síi yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí inú yín sì dùn, nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó ti wà ṣáájú yín. Matiu 5:10–12
BÍ A ṢE N BẸ̀RẸ̀
Wọ́n mú Celio Secondo Curione ní ọdún 1523 nítorí pé ó n jíròrò l'órí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ràn ẹ̀dá ènìyàn ará Ítálì tí ó ní ìfẹ̀ púpọ sí ẹ̀kọ́ Martin Luther, wọ́n rán Curione lọ sí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, ní ibi tí àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì ti rọ̀ ọ́ láti ro'nú jinlẹ̀ l'órí bí ó ṣe jẹ́ wípé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tẹ sí iwájú láti máa ka ìwé àwọn Alátúnṣe Ìsìn, ó ń kéde iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tẹ́ etí sí'lẹ̀.
Ni òtítọ́, Ìwé Mímọ́ wú u l'órí tó bẹ́ẹ̀ dé ibi pé ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín ó yọ àwọn egungun kan kúrò nínú àpótí ohun ìrántí ẹni mímọ́ kan, ó sì fi Bíbélì kan rọ́pò pẹlú àkọsílẹ̀ yìí tí ó ń mú ẹni gbọ̀n rìrì: "Èyí ni Àpótí Májẹ̀mú ní ibi tí a ti rí àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó jẹ́ òtítọ́; ìwọ̀nyí ni àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ òtítọ́."
Ìtàn yìí ṣe àpèjúwe ojú àmi ọkàn Jésù nínú àwọn ọ̀rọ̀ ibukún ikẹ́yìn rẹ̀. Nítorí agbára ìgbàlà ìhìnrere, Curione fi ìdùnnú fi ara da inúnibíni àti ìfìyàjẹni, ó mọ̀ wípé òkodoro òtítọ́ nípa ìjọba Kristi ṣe pàtàkì ju ààbò tàbí ìtẹ́wọ́gbà ẹni lọ.
ÒYE LÁTI INÚ ÌFỌKÀNSÍN
Bí ìlérí àlàáfíà Bíbélì ṣe jẹ́ ogún gbogbo onígbàgbọ nínú Jésù ni ó ṣe pàtàkì wípé ki àwa náà, bíi tirẹ̀, gbé àgbélèbú kan.
ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ
Ọ̀rọ̀ Ìbùkún kẹjọ àti ìkẹsàn-án sọ ìdí méjì tí a fi ka inúnibíni sí ìbùkún: ní ìgbà tí ó bá jẹ́ nítorí òdodo (Matiu 5:10), tàbí ní ìgbà tí a bá bú ẹni tàbi tí a kán ẹní ni àbùkù nítorí orúkọ Jésù (Matiu 5:11). Ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́yìn yìí jẹ́ àlàyé àti àfikún sí ti àkọ́kọ́, nítorí pé ìjẹ́rìí tí à ń ṣe ní gbangba nípa òdodo dá l'órí bí a ṣe ń bá Jésù rìn.
Ní àkókò àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ yìí, bíi àjálù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni àwọn Kristẹni ń gbà mú ìjìyà wá sí orí ara wọn. Àwọn tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ ìkórìíra tàbí èròǹgbà ìdìtẹ̀ láì ní ààlà máa ń mú kí àwọn ènìyàn fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n pa wọ́n tì l'órí ìkànnì àjọlò orí íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn tí ń gbèjà ìwà ìbàjẹ́ tàbí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn olóṣèlú tí wọ́n fẹ́ràn jù lọ (ní àwọn ẹ̀ka méjèèjì) ni a lè pè ní alágàbàgebè. Àwọn wọ́nnì tí n ṣe àwáwí fún irúfin ìwà òtítọ́ nípa sísọ wípé ẹ̀gbẹ́ keji ǹ ṣe ohun tí ó burú jùlọ ni a fi ṣe ẹlẹ́yà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń hu ìwà oniròoro "eminìkan-kọ́".
Amọ́ o, a kò gbọdọ̀ ṣe àìsọ wípé Kristẹni òde òní, àní ní Ìwọ̀ Oòrùn tí a ní èrò wípé ó gba tiwọn rò, ń fi ojú wi iná inúnibíni nítorí òdodo. Àwọn tí ó bá kọ̀ láti ní ọwọ́ nínú gbígbé ìgbé ayé tí kò bá Bíbélì mu, èyí tí ó wọ́pọ̀ ní àárín àwọn oníṣòwò àti àwọn ọ̀mọ̀wé, lè bá ara wọn nínú ipò tí wọ́n á ti máa yọ wọ́n l'ẹ́gbẹ́, tí wọ́n á máa fà wọ́n lọ sí ilé ẹjọ́, tàbí tí wọn ò ní ní iṣẹ́ ní ọwọ́. L'ẹ́yìn òde Ìwọ̀ Oòrùn, àwọn Kristẹni lè d'ojú kọ onírúurú ewu nítorí kíkọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn—tàbí kìkì ìwà ọ̀daràn a tí ṣe àfarahàn gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi.
Ìtàn Ìhìnrere tí ó tóbi yìí gbà wípé wíwà nínú Kristi ń ṣe àpèjúwe ohun gbogbo nípa wa - gbogbo ìlépa, ìgbòkègbodò, ète, ìdí àti ìjùmọ̀sòpọ̀ - ìdánimọ̀ àti ìpè tí yóò jẹ́ ẹ̀dùn fún òye aráyé.
ÌMÚLÒ
Báwo ni inúnibíni ṣe jẹ́ ìhìnrere, tí ó fi jẹ́ wípé ó ń fún ni ní ayọ̀? Ní ṣókí, àǹfààní ni ó jẹ́ láti wà l'áàyè nítorí Kristi. Ó jẹ́ ìgbàgbọ ayọ̀ láti dìrọ̀ mọ́ èrè ìlérí ìjọba ọ̀run nlá nì. Bíi ti Ábúráhámù, àwọn ọmọlẹ̀yìn Kristi ń wo ọ̀nà fún ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ gbọn-in gbọn-in, èyí tí Ọlọ́run jẹ́ olùṣẹ̀dá àti olùpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ (Heberu 11:10). Àmọ́, ó ba ẹni ní inú jẹ́ wípé ayọ̀ yìí kò bá ayé yìí mu, nítorí pé ayé yìí ń wá ìjọba òmíràn.
Njẹ́ ò n gbé ìgbésí ayé tí ó fa àwọn ìbéèrè tàbí ìyàlẹ́nu láti ọ̀dọ̀ àwọn aládugbó rẹ bí? Inúnibíni? Báwo ni ayọ̀ àti ìdùnnú rẹ ṣe pọ̀ tó bi o ṣe ń gbé ìgbésí ayé fún Kristi? Ǹjẹ́ o mú ara tán láti jẹ ìyà kí o lè ní irú ayọ̀ àrà ọ̀tọ̀ tí ó wà ní inú Ìjọba náà? Kí ni o lè máa fà ọ sí ẹhin láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa?
Láti kà sí iwájú síi l'órí àwọn Ọrọ-Ibukún, ṣe àyẹ̀wò The Upside Down Kingdom: Wisdom for Life from the Beatitudes láti ọwọ́ Crossway, ní ibí yìí: https://www.crossway.org/books/the-upside-down-kingdom-tpb/
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.
More