Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Ọjọ́ 4 nínú 8

Tọ́ Ọ Wò Kí O Ríi

Alábùkúnfún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó. Mátíù 5:6

BÍ A ṢE Ń BẸ̀RẸ̀

Gbogbo wa ni a mọ bí ebi ti ń rí ní ara. Bí ebí bá pa ìkòkò, yóò sun ẹkún, àgbàlagbà tí ebi bá pa ńkọ́, wọn á máa kan'ra. Bẹ́ẹ̀ ni a mọ irúfẹ́ ebi tí ó ma tì wá láti rúbọ ohun ìní àti láti gbé ǹkan ńlá ṣe; ebi tí ó gba gbogbo ọkàn wa kan, tọ́ ipasẹ̀ wa, tí ó sì ń mú ìlépa wa ní ipọn síi. B'ó pẹ́ b'ó yá, ebi yìí a máa tukọ̀ ìhùwàsí wa. Bí àwọn àgbà ti máa ń wí, “Ohun tí ẹyẹ bá jẹ ni ẹyẹ máa gbé fò,” èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa ǹkan tí ẹ̀mí pẹ̀lú.

Ní ìgbà tí gbogbo ìlépa wa bá jẹ́ sí ipa ìmọ̀-tara-ẹni nìkan, ìṣekusẹyẹ, kíkó ọrọ̀ tí kò wúlò jọ, àti àìjẹ́-olótìtọ́ sí ọkọ tàbí aya, gbogbo ìwà yíì ni yóò padà jẹ yọ nínú ìhùwàsí wa. Bíi a-rí-oúnjẹ-má-mẹ́nu-kúrò tí máa jẹ àjebánu, tí yóò tún jẹ síi tí ó bá rí òmíràn, ó ṣeé ṣe fún wa láti yẹ ẹsẹ̀ láti inú ìgbọ̀jẹ̀gẹ̀ kékeré sí inú ìwà ìparun tí ó rinlẹ̀ bíi ojúkòkòrò, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, owú àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míràn tí ó lè ṣe ikú pa ẹni. Ọ̀jọ̀gbọ́n James K.A. Smith sọ ọ̀rọ̀ nípa bí ó ti ṣe pàtàkì tó fún wa láti ṣe “àtúntò” àwọn ìlépa wa. Èyí túmọ̀ sí jíjọ̀wọ́ gbogbo àwọn ìpòǹgbẹ àti ìlépa wa sí ẹsẹ̀ ìkápá Kristi.

A pè wá láti lépa fún ìwà òdodo.

ÒYE LÁTI INÚ ÌFỌKÀNSÌN

Òdodo tí à ń sọ wípé kí a ṣe àwárí rẹ̀ ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ń ṣe iṣẹ́ ìràpadà—oore-ọ̀fẹ́ tí ń bù kún fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ní ibi tí a ti ní'lò rẹ̀ jùlọ: ní inú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run, ní inú ìsọdọ̀tun ọkàn wa, àti ní inú àwọn ìlànà tí a fi ń jọ gbé papọ̀ ní àwùjọ.

ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ

Òdodo Ọlọ́run a máa mú ògo rẹ̀ fi ara hàn bí ó ti ń fi ọwọ́ àánú rẹ̀ na ìgbàlà sí wa. Jésù jẹ́ ìwàláàyè òdodo yìí, àti wípé ní báyìí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á pẹ̀lú ìgbàgbọ́ máa jẹ ìgbádùn ìbùkún ìràpadà rẹ̀. Ní ìgbà tí Mátíù, agbowó òde, ro'nú p'ìwà dà, ó ní ìrírí ìdájọ́ àti ìbùkún Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ó ti rí fún àwọn olówò nọ̀bì àti àwọn tí a ti rò pin gẹ́gẹ́ bíi “ẹlẹ́ṣẹ̀.” Nítorí náà, Jésù sọ fún àwọn adarí ẹ̀sìn, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín.” (Mátíù 21:31). Ṣé ó wà yẹ kí ó ya'ni ní ẹnu wípé àwọn adarí Júù ìgbàanì lépa láti mú u? Ìjọba arọ́pò kan wá ń lépa ìjẹ gàba l'órí ọrọ̀ ẹ̀sìn wọn—ní òtítọ́, ìyẹn ìjọba Ọlọ́run.

“Ìbùkún yìí,” ni Donald Hagner sọ wípé, “kìí ṣe fún àwọn tí ó ń gbé ǹkan ṣe, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ó ṣe tán láti gbà á wọlé.” A gbọ́dọ̀ làkàkà láti máà rí ohun kankan ní inú ara wa tí ó yẹ fún ojú rere Ọlọ́run. Láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni a ti gbà wá là nípasẹ̀ ètò àtọ̀runwá. Ọ̀nà míràn wo ni a fẹ́ gbà ṣe àlàyé bí Ọlọ́run ti tẹ́ ọwọ́ gba àwọn aláìnígboyà bíi Ábúráhámù, pẹ̀lú àwọn alágbèrè àti apànìyàn bíi ti Dáfídì? (Wo Róòmù 4:1-8.) Àti wípé, báwo ni a yóò ti ṣe àlàyé ìgbàgbọ́ tiwa?

ÌMÚLÒ

Ní ibi tí a ti ń ja ìjàkadì fún ìhìn rere ti ìdáláre nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nìkan, àwọn Alátùńṣe sọ wípé ìgbàgbọ́ wa kò leè dá wà. Fún àpẹẹrẹ, Calvin ní ìdánilójú wípé “ìlépa wa kìí ṣe fún ìgbàgbọ́ tí kò ní iṣẹ́ nínú bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe fún ìdáláre tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú.” Ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Kristi, a máa wà padà ní ìbápàdé pẹ̀lú iṣẹ́ ìsọdọ̀tun ti Ẹ̀mí, èyí tí yóò wá mú èso òdodo jáde wá. (Gálátíà 5:22–23).

Ní ọ̀nà yìí ni Jésù fi ń yí àwọn ìlépa wa padà láti inú wá. Irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀, bí Martin Luther ti sọ, “a máa ṣe iṣẹ́ a sì máa tiraka pẹ̀lú gbogbo ipá rẹ̀ láti mú àlàáfíà àti ìwà-pẹ̀lẹ́ oníkálukú, bẹ́ẹ̀ni... wọn yóò sì máa ṣe ìmúdúró nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, nípa ìlànà àti àpẹẹrẹ.”

Àwọn tí ó ní ìrírí ebi àti òùngbẹ fún òdodo yóò ma ṣe àfihàn pé a ti tẹ́ wọn l'ọ́rùn bí wọ́n ti ń gbé ìgbésí ayé òdodo lóòrè-kóòrè (síbẹ̀ pẹ̀lú kùdìẹ̀-kùdìẹ̀). Ǹjẹ́ ebi àti ìpòngbẹ fún òdodo wà nínú ayé tìrẹ? Ọ̀nà wò ní ìlépa titun yìí fi ń jẹ yọ nínú ayé tìrẹ?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/