Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Ọjọ́ 7 nínú 8

Ki Àlàáfíà Wa Pẹ̀lú Rẹ

Alábùkúnfún ni àwọn onílàjà: nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó ma pè wọn. Matiu 5:9

BÍ A ṢE Ń BẸ̀RẸ̀

Ọmọ ìkọ́ṣẹ́ kan béèrè ní ọwọ́ mi ní àipẹ́ yìí pe, “Kíni ohun ìdíwọ́ tí ó ṣe kókó jù lọ tí kò fi sí àlàáfíà nínú ìjọ ní òní?” Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀, àwọn èdèàiyedè bíi mélòó kan sọ sì mi ní ọkàn: òwú pẹ́pẹ́ẹ̀pẹ́, ìlépá tí ó n da ìṣọ̀kan rú, ìjà abẹ́lé tí ó ń sán ìgbéyàwó ní eegun tí ó sì n fa ìkọ̀sílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ju gbogbo èyí, èyí tí ó tayọ jù lọ tí ó lè jẹ́ gbongbo irọ́kẹkẹ tí ó ta ko àlàáfíà nínú ìjọ́ òde òní— ẹgbẹ́ òṣèlú tí o gbé àṣà ní arugẹ (ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní inú wọn jẹ́ òtítọ́) ju ìgbìmọ̀ tí ó ga jù lọ.

Ní òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristẹni ni wọ́n máa ń fi ègbẹ́ òṣèlú wọn wé ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń mú ipò tí ó máa n fi àwọn èdè àti ọ̀rọ̀ ìbínú ṣe ààmí ìdánimọ̀ fún ara wọn. Àwọn tí ó wà ní ẹgbẹ́ òṣèlú míràn wayí, á wá jẹ́ bíi àwọn tí ó burú jáì, tí kò sì ní èrò tí ó bá tiwọn dọ́gba. Bẹ́ẹ̀ ni iru ìpínyà tí ó wà ní àárín ẹgbẹ́ òṣèlú ìtẹ̀síwájú àti ti consafetifu.

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ìjọ da ojú kọ ogún yìí láti ọ̀nà míràn?

ÒYE LÁTI INÚ ÌFỌKÀNSÌN

Jíjẹ́ onílàjà kìí ṣé wípé kí a dára tàbí kí a lè ṣe oore. Kìí sìí ṣe pípa iná ìṣòdì. Jíjẹ́ onílàjà jẹ́ ètò Ọlọ́run fún gbígbé ní inú Kristi ní agbègbè wá.

ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ

Bí Ọlọ́run ṣe na ọwọ́ àlàáfíà sí wá fi ara jọ bí ó ṣe ń ṣe ìdájọ́ fún wá. Bí Pọ́ọ̀lù ti se àlàyé, Ọlọ́run fi àlàáfíà lọ̀ fún ẹnikẹ́ni tí a ti dá ní àre “nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa” (Romu 5:1). Fífi ọkàn wa sí ohun ti Ẹ̀mí ni ó má ń já sì àwọn òdiwọ̀n àlàáfíà (Romu 8:6). Ní àkótán, ó jẹ́ ìpè wa láti jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run ṣàn láti inú wa nípa lílépa “ohun tí ń fún ni ní àlàáfíà àti fún ìdàgbàsókè mùtúmùwà” (Romu 14:19). Ìṣísẹ̀ntẹ̀lé yìí ṣe kókó nítorí wípé a kò lè fún ẹlòmíràn ní ohun tí ọwọ́ wa kò tíì tó.

Àníyàn, ní tirẹ̀, lè gba àlàáfíà wa ní ọwọ́ wa. A máa ń ní àkókò àníyàn àti ìbínú — ó lè jẹ́ fún ọjọ́ méló kan, ọ̀sẹ̀ díè, tàbí ìgbà díè— ṣùgbọ́n, a dúpẹ́ ní ọwọ́ Ọlọ́run wípé kò kìí pẹ́ lọ títí. Òhún tí ó jinlẹ̀ tí ó sì kéré jù ni ìpòrúùrú ọkàn wa nípa ìdánimọ̀ wá gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọlọ́run, tí Ẹ̀mí Mímọ́ n gbe inú rẹ̀. Irú ìbágbé yìí a máa tẹ orí ọkàn wa ba, yóò sì dárí wá ní ipa ọ̀nà tí ó lè ní ìdádúró ṣùgbọ́n tí ó dájú wípé á já sì àlàáfíà.

Ní kúkúrú, ìpè wá sí jíjẹ́ onílàjà jẹ́ fífi ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ ń ṣe ńi inú kọ̀ọ̀rọ̀ ọkàn wa hàn ní gbangba—ṣíṣe ìtọ́jú ati àfihàn iṣẹ́ Krístì.

ÌMÚLÒ

Dípò kí a máa fura kí a sì máa ní ìjà nínú óókan-àyà wa, báwo ni ì bá ti rí bí a bá ń fi sùúrù àti ṣíṣe oore bá ara wa lò, kí a sì máa fi ara da ohun gbogbo ní orúkọ Kristi (1 Korinti 13:4, 7)? Báwo ni ì bá ṣe rí bí àwa tìkára wa bá bá àwọn ẹlòmíràn ṣe bí a ti fẹ́ kí wọ́n bá wa ṣe (Matiu 7:12; Luuku 6:31)? Báwo ni ì bá ṣe rí bí a bá fi ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí ọkàn, èyí tí ó wípé, “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ yin kí ó dà pọ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ ní ìgbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ bí ẹ̀yin ó ti mã dá olúkúlùkù ènìà lóhùn” (Kolose 4:6)?

Njẹ́, fún àpẹẹrẹ, a lè ṣe ìlérí láti dá ààbò bo ọmọ inú oyún tí a kò tíì bí ní pípa ètò Ọlọ́run fún ẹbí mọ, àti dídojúkọ ìwà ìrẹ́jẹ ẹléyàmeya bí? Irú jíjẹ́ onílàjà báyìí kò nílò wípé kí a pa àwọn ìmò wá nípa Ọlọ́run tì. Ohun tí ó ṣe kókó ni wípé kí a fi ìwà jọ Kristi tí ó kú ní orí àgbélébùú fún wa, ẹni tí ó fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọ̀tá (Matiu 5:44).

Ipò wa gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ darí wa sí fífi jíjẹ́ ónílàjà ṣe àṣà. Irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ kìí bá ọ̀fẹ́ dé, a kò sì tà á ní ọ̀pọ̀. Alàáfíà Ọlọ́run tí ó jí Jésù dìde kúrò ní inú òkú yóò jẹ́ kí ó lékè (Heberu 13:20).

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/