Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Ọjọ́ 6 nínú 8

Rírí Ọlọ́run

Alábùkúnfún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run. Mátíù 5:8

BÍ A ṢE N BẸ̀RẸ̀

L'ẹ́yìn tí ojú rẹ̀ fọ́ ní ìgbà tí ó wà ní ọmọdé nítorí àìbìkítà dókítà, ó lé ní orin ìyìn 9000 tí Fanny J. Crosby kọ, pẹ̀lú “Ó Dá Mi Lójú Mo Ní Jésù,” “Fà Mi Sún Mọ́ Àgbélébùú,” àti “Olúwa Èmi Ṣáà Ti Gbóhùn Rẹ.” Ẹ̀mí àgbàyanu tí ó ní ni ó mú kí Crosby kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin. Hugh Main, ọ̀kan l'ára àwọn tí ó ń bá a ṣe iṣẹ́ sọ pé, "Ó lè ka orin ìsìn méjì ní ẹ̀ẹ̀kan náà, tí ó ń yí padà ní àárín àwọn ìlà nínú ewì kọ̀ọ̀kan àti bíbá akọ̀wé méjì ṣe iṣẹ́."

Àmọ́ apá kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni èyí jẹ́. Fún ohun tí ó lé ní ogún ọdún, ó ṣe àbẹ̀wò àwọn tí wọ́n pa tì, tí wọ́n sì tẹ ẹ̀mí wọn ní ojú mọ́'lẹ̀ ní ìlùú Manhattan. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Crosby máa ń fún àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìṣírí tí ó ń tọ́'ka sí òpin ìgbésí ayé ní ìgbà tí àwọn onígbàgbọ́ bá bá Kristi pàdé ní ojúkoojú. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣe àpèjúwe ìrètí tí ó ga jù lọ yìí gẹ́gẹ́ bíi ìran aláyọ̀ (1 Kọ́ríńtì 13:12).

OYÉ LÁTI ÌNÙ ÌFỌ̀KÀNSÍN

Ọlọ́run máa ń ṣe àyẹ̀wò àwon erò ọkàn wa, ìdí tí a fi ń ṣe ohunkóhun, àti ìwa ìkọ̀kọ̀ wa. Irú èrò ọkàn àti ìdí wọ̀nyí ni olórí ohun tí ó ń darí ìjọba náà.

ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ

Ìṣòro náà ni pé ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí kò mọ Ọlọrun ti yí ojú sí inú ara rẹ̀, ó sì ti jìnà sí Ọlọ́run. Augustine sọ pé èyí máa ń yọrí sí irọ́ pípa àti ìgbéraga, èyí tí ó máa ń yọrí sí ìdálẹ́kun àti rògbòdìyàn sí iwájú sí i. Ọkàn ni ó wà ní ìdìí ìṣòro náà. Kódà àwọn ìgbésẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ àti ti àìmọtara-ẹni-nìkan wa—iṣẹ́ ìsìn wa sí àwọn ẹlòmíràn àti wíwá ire gbogbo ènìyàn—kò sí bí wọn ò ṣe ní di ohun tí ó ń mú ẹni gbé ara ga. Ẹ̀ṣẹ̀ tí ó fi ara sin ni a sábà máa ń bo mọ́lẹ̀ ní ìgbà tí á bá sọ pé a jẹ́ oníwà mímọ́.

Ní ìgbà tí Augustine ń bá Ọlọ́run so ọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Ìwọ fún ara rẹ ni ó dá wa fún ara rẹ, ọkàn wa kò sì ní ìsinmi títí yóò fi sinmi ní inú rẹ.” Ó lo ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo “ọkàn”, kì í ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ “àwọn ọkàn,” èyí tí ó fi hàn pé ẹ̀dá ènìyàn ní ọkàn kan náà. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó ní ìlò rẹ̀—kí òfo wa lè kún fún ìwàláàyè Ọlọ́run tí ń sọ ẹni di mímọ́. Èyí gan-an ni ohun tí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣe nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́, ìyípadà tí ó máa mú kí a já ọwọ́ nínú àìbìkítà.

Ìrírí yìí— ìgbésẹ̀ láti ìfọ́jú de ìríran nípa ti ẹ̀mí ni ọ̀nà ìgbàlà. Ní ìgbà tí Augustine ń wàásù fún ìjọ tí ó wà ní ìlú Hippo, ó sọ pé, “Gbogbo iṣẹ́ wa ní inú ayé yìí ni láti mú ojú ọkàn padà sí ìlera èyí tí a fi leè rí Ọlọ́run.” Ìwòye tí ó ju ìwòye lọ ní èyí. Ìran Ọlọ́run ni.

ÌMÚLÒ

Ìwàásù yìí fi oore-ọ̀fẹ́ rán wa l'étí pé ohun tí a gbá ojú mọ́ kò ṣeé yà kúrò nínú ohun tí ó wà ní ọkàn wa. Àìmọ́ àti ìran Olọ́run ko leè wà papọ̀. Àwa tí a ti wo Ẹni tí a gbé dìde fún ìdáláre wa, a kò gbà wá là láti máa bá ìgbésí ayé àìmọ́ nìṣó. Dípò èyí, a ti gbà wá ní ọwọ́ ìwà àìmọ́, a sì ti di ẹni tuntun, ìyípadà tí ó ń wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé (láti ojú ìwòye wa) èyí tí ó túbọ̀ ń mọ rírì Kristi ju àwọn ohun asán tí ó máa ń wù wá jùlọ.

Àwọn tí ó ń wá ìjẹ́mímọ́ náà ń wá Olúwa, bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ ní aginjù, yóò rí àwọn méjèèjì, yóò sì mú òùngbẹ wọn kúrò títí láé. Ní ibo ni ọkàn rẹ wà?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/