Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Ọjọ́ 3 nínú 8

Ìwà Pẹ̀lẹ́ Nínú Ayé Alátakò

Alábùkúnfún ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí wọn yóò jogún ayé. Mátíù 5:5

BÍ A ṢE N BẸ̀RẸ̀

Ní ọdún 1095, Póòpù Urban Kejì pè fún ohun tí wọ́n mọ̀ sí Ogun Ìsìn Kíní láti gba Jerúsálẹ́mù padà l'ọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí, pẹ̀lú igbe Deus Vult, tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run ni ó fẹ́ ẹ.” Pẹ̀lú ẹ̀mí kan náà, ọ̀pọ̀ jagunjagun (láti ilẹ̀ Potogí àti Sípéènì) wá láti tan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Amẹ́ríkà—ìtàn ìwà oǹrorò òmíràn ní orúkọ Jésù. Ogun Ọgbọ̀n Ọdún náà (1618 si 1648) tún wá sì wa ní ọkàn, ní ìgbà tí àwọn Kátólíìkì àti àwọn ìjọ Alátakò ní ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ ní ojú ogun, tí wọ́n lo àwọn ohun ìjà àgbélẹ̀rọ, tí ó yọrí sí ikú ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.

Gbogbo elèyí mú wa béèrè pé: Kí ni ipa tí ó bá ojú mu gan-an nínú ìgbésí ayé Kristẹni—ìyẹn ìṣàkóso “agbára láti ibi gíga wa” (Lúùkù 24:49) nípasẹ̀ èyí tí ìjọba náà fi ń tẹ̀ sí iwájú nínú ayé yìí?

ÒYE LÁTI INÚ ÌFỌKÀNSÌN

Kókó ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ìfẹ́ tí ń fi ara-ẹni fún Ọlọ́run, tí a rí pẹ̀lú agbára nínú bí Krístì ti fi ẹ̀mí Rẹ̀ lé'lẹ̀ fún wa. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ sí ìdàrúdàpọ̀ nínú ìtumọ̀ ìrẹ̀lẹ̀ àti àìpéye. Ní ọ́nà tí kò bá ara wọn mú, a lè túmọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ gẹ́gẹ́ bíi agbára tí ó tútù, tí Ẹ̀mí Mímọ́ ń ṣe àkóso re, èyí tí yóò sì j'ogún ilẹ̀ ayé.

ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ

Ẹ̀kọ́ wa tí òní sọ báyìí pé, "Alábùkúnfún ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí wọn yóò j'ogún ayé". (Mátíù 5:5) Ọ̀rọ̀-ìṣe náà “j'ogún” tọ́'ka sí ohun ìní tí ó dúró ṣinṣin, ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi lé wa l'ọ́wọ́. Ṣùgbọ́n kíni èyí túmọ̀ sí—láti ní ilẹ̀ ayé? Sáàmù 37 sọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́kàn tútù tí ń j'ogún ilẹ̀ náà (ilẹ̀ Ísírẹ́lì). Àwọn alábùkúnfún onírẹ̀lẹ̀ ni àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa. Wọ́n fi ìbínú sí'lẹ̀. Wọ́n fi sùúrù dúró—Ọlọ́run sì fi Ilẹ̀ Ìlérí fún wọn gẹ́gẹ́ bíi èrè ìdúró wọn.

Ṣùgbọ́n àyọkà wá kò sọ pé “ilẹ̀.” Jésù sọ pé onírẹ̀lẹ̀ yóò j'ogún “ayé”. Ìbùkún Ọlọ́run ti di ti gbogbo àgbáyé. Nísinsìnyìí ìjọba náà jẹ́ ti àwọn ènìyàn láti inú gbogbo ẹ̀yà, ahọ́n àti orílẹ̀-èdè. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlè nípa ẹ̀sìn pe Ìjọba náà ní “èyí tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ tí irú rẹ̀ kò tí ì sí.” Ògún tí ó kún ojú òṣùwọ̀n yóò wà ní ọjọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n àwọn ìbùkún náà ti bẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú ìrẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run… ẹ̀rí ọkàn mímọ́… àlàáfíà… àti èso tí ẹ̀mí.

ÌMÚLÒ

Ní gbogbo ìjọba Krístì, a kò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n mú ara sí'lẹ̀ láti darí ìjọ Krístì pẹ̀lú ìwà tútù—ìyẹn ni pé, agbára pẹ̀lẹ̀kùtù, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ń ṣe àkóso rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó jókò s'ẹ́yìn, wọ́n sì dúró de àwọn ẹlòmíràn láti darí, láti pinnu, àti láti máa bá iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà nìṣó. Àwọn ìjọ ń rẹ̀wẹ̀sì—èṣù sì ń rín ẹ̀rín èké. Ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, a gbàgbé pé kìnìún ni Krístì í ṣe, pàṣán l'órí ẹ̀sìn aláìlérá, tí ó pe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ní ọwọ́ nínú ogun tí ẹ̀mí.

Láti rí agbára ìrẹ̀lẹ̀ tí a kò leè ṣe àlàyé rẹ, a kò gbọdọ̀ wo ìwà tútù fún ara rẹ̀. Ẹni tí ó yẹ láti wò ní Jésù Krístì Olúwa, Ọba ìwà tútù tí ó rẹ́ ara rẹ̀ sí'lẹ̀ dé ojú ikú, pàápàá ikú l'órí àgbélébùú (Filippi 2). Pẹ̀lú irú ìran bẹ́ẹ̀ ní iwájú wa, a yóò ní ìmísí láti sìn nínú ìjọ àti ní ilé pẹ̀lú òkun ní pẹ̀lẹ́-kùtù, àtí ìṣàkóso Ẹ̀mí. Ní ìgbà náà ni ayé tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìforígbárí yóò rí ìyàtọ̀ tí ìwà tútù tí ó ń bù ọlá fún Kristi n ní.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/