Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Ọjọ́ 1 nínú 8

Òṣì Tí Ó Sọ Èniyan Di Ọlọ́rọ̀

Alábùkúnfún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Matiu 5:3

BÍ A ṢE Ń BẸ̀RẸ̀

Ní ìgbà kan rí Mike Vetrone jẹ́ olùtà òògùn olóró fún ogunlọ́gọ̀ àwọn tí lílo òògùn olóró heroínì ti di bárakú fún. Ní ìgbà tí ó ní ìmọ̀lára pé òun kò ní ará, tí ó di wí pé ìgbà gbogbo ni wọ́n ń halẹ̀ gbígba ẹ̀mí rẹ̀ mọ́ ọn, èrò pé kí òun fi òpin sí gbogbo rẹ̀ yọ sí i. Ní àárọ̀ ọjọ́ kan tí ojú ọjọ́ ṣe gùdẹ̀gùdẹ̀ ní South Florida, Mike lọ sí Big Apple Bagel, ilé oúnjẹ tí ó fẹ́ràn jù, láti ra oúnjẹ àjẹkẹ́hìn rẹ̀. Ní ìgbà tí ó padà dé ilé, ó tan ẹ̀rọ̀ tẹlifísàn rẹ̀ kí ó má baà dá wà. Oníwàásù orí tẹlifíṣàn kan ni ó rí tí ó ń ké igbe tantan pé, "Ayé ní ọ̀nà tí yóò fi di ọrùn ẹ̀wù rẹ mú, tí yóò sì fi tipátipá mú ọ kúnlẹ̀.”

Mike yí agbagbe tẹlifíṣàn rẹ̀ sí òkè.

“Ẹ̀wọ̀n kan wà tí ó de gbogbo ọkàn," oníwàásù náà tẹ̀ sí iwájú, "ẹ̀wọ̀n ọ̀hún sì ni ẹ̀ṣẹ̀—ohun àfẹ́sódì tí ikú àti àjínde Jésù ti gbà wá l'ọ́wọ́ rẹ̀.” Ní òjijì, bí oníwàásù orí tẹlifíṣàn yí ṣe ń pe àwọn olùwòran pé kí wọ́n gba Krístì, Mike rí pé òun ń pariwo, "Bẹ́ẹ̀ni" sí tẹlifíṣàn. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kò sì dà bíi pé ó dá wà mọ́.

Ohun tí Mike bẹ̀rẹ̀ kìí ṣe òpin ìgbésí ayé rẹ̀ ṣùgbọ́n ìbẹ̀rẹ̀ ayé ọ̀tun.

ÒYE LÁTI INÚ ÌFỌKÀNSÌN

Ní ìgbà tí òye ipò òṣì wa nínú ẹ̀mí bá yé wa, a ti ṣe tán láti gba àwọn ọrọ̀ ti Ọba náà. Ìjọba náà kìí ṣe fún àwọn tí ó ń já nnkan gbà, ṣùgbọn fún àwọn oníròbìnújẹ́—àwọn tí ipá wọ́n ti pin tí wọ́n sì tọ Ólọ́run wá pẹ̀lú ọwọ́ òfo.

ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ

Gbólóhùn "ìjọba ọ̀run" wà jákèjádò ìwé Mátíù ó sì túmọ̀ sí "ìjọba Ọlọ́run". Ó ń ṣe àpèjúwe ìgbésí ayé òtítọ́, àlàáfíà, mímọ́ àti ayọ̀ tí à ń rí nípasẹ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Irú àwọn ìbùkún báyìí d'ojú kọ àwọn òrìṣà wa—àwọn ọlọ́run ìtùnú, àṣeyọrí, àti ìgbéraga orílẹ̀ èdè—àti ìlérí nnkan tí ó túbọ̀ tóbi sí. Ní òtítọ́, àwọn òrìṣà wulẹ̀ jẹ́ àyídáyidà àti ẹ̀dà nnkan tí ìjọba òtítọ́ àti ìtẹ́nilọ́rùn jẹ́. Nítorí náà, àwọn Ìbùkún Jésù ní orí òkè dá lé ìjọba ọ̀run: "Alábùkúnfún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run” (Matiu 5:3; cf. 5:10).

Ṣe àkíyèsí bí Jésù ti ṣe àpèjúwe ìjọba ọ̀run gẹ́gẹ́ bíi "tiwọn". Fífi ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ gbólóhùn jẹ́ kí ó dà bíi pé ìjọba ọ̀run wà fún àwọn ìṣọ̀wọ́ yìí, òtòṣì ní ẹ̀mí, àwọn tí wọ́n ti yà sí ọ̀tọ̀ tí wọ́n sì ti gbàgbé sí ẹ̀gbẹ́ kan. Kìí ṣe fún àwọn tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ayé, tí wọ́n sì ń wà ní ìṣàkóso ní ìgbà gbogbo. Kìí ṣe fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú ara wọn, tí wọ́n ní ipa àbímọ́ láti jẹ́ olúborí ní gbogbo ọjọ́. Gẹ́gẹ́ bí Martin Luther ti kéde ní orí ibùsùn tí ó kú sí, "Alágbe ni gbogbo wa; èyí jẹ́ òtítọ́.”

ÌMÚLÒ

Àwọn ènìyàn ti àkókò Jésù ń retí olùdándè bíi Jòṣúà tàbí Dáfídì, olórí ogun tí yóò borí àwọn Rómù tí yóò sì fi ìjọba ti ayé lélẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, a mọ̀ ọ́n sí ọ̀rẹ́ àwọn agb'owó òde—agbo àwọn agbẹ̀hìnbẹbọjẹ́ tí wọ́n fi ara mọ́ àwọn ọ̀tá olóṣèlú.

Ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ Olùgbàlà wa, a kò nílò láti máa gba ìjà ara wa jà tàbí kí ó jẹ́ pé ohùn tiwa ní yóò máa lékè. Àwọn Krìstẹ́nì tí wọ́n jẹ́ òtòṣì nínú ẹ̀mí lè gbé pẹ̀lú kí wọ́n bà wọ́n ní orúkọ jẹ́ tàbí kí wọ́n ṣì wọ́n gbọ́. Gẹ́gẹ́ bíi Jésù ní iwájú Hẹ́rọ́dù Áńtípà—wọ́n lè má f'ọhùn. Irú òṣì báyìí ṣe pàtàkì ní ìgbà tí a bá ń k'ojú ìdánwò láti dá èsì ìbínú padà fún "ọ̀tá" wa tí èrò rẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ àwùjọ tàbí ti ìṣèlú yàtọ̀ sí tiwa.

Báwo ni o ṣe lè jẹ́ àpẹẹrẹ òtòṣì nínú ẹ̀mí, pàápàá ní àárin àwọn tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti ja iyàn?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Upside Down Kingdom: An 8 Day Study Through the Beatitudes

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/