Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

Ojú Àánú
Alábùkúnfún ni àwọn aláànú, nítorí wọn óò rí àánú gbà. Mátíù 5:7
BÍ A ṢE Ń BẸ̀RẸ̀
Obìnrin kan ẹni àádọ́rin ọdún tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Marinella Beretta ni wọ́n rí òkú rẹ̀ ní Prestino, ní ìtòsí odò-adágún Como ní ìhà àríwá Italy. Ipò ìjókòó ni àwọn ọlọ́pàá bá a ní ibi tábìlì rẹ̀ ní ìgbà tí wọn rí òkú rẹ̀ ní ẹ̀yìn ọdún méjì ó lé tí ó ti kú. Ó jẹ jáde pé àwọn aládùúgbò Marinella kò tíì rí i láti ọdún méjì àbọ̀ ó kéré tán. Obìnrin náà jẹ́ “adánìkanwà ẹ̀dá,” ni ohun tí Massimo Gramellini, oníròyìn tí ó ṣe iṣẹ́ l'órí ìṣẹ̀lẹ̀ náa kọ. “Àwọn ènìyàn máa ń dà nìkàn kú ni. A tún n dà nìkàn gbé ayé, èyí gan-an tún fẹ́rẹ̀ burú jù ú lọ.”
Àwọn ọ̀rọ̀ ìparí ìwé-àpilẹ̀kọ náa yí ẹni ní ọkàn padà: “Àṣírí ìgbé ayé àdììtú tí Marinella gbé ní ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn tí ó tì gbọn-in-gbọn-in kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ tí ó já ẹni l'áyà. Ìbànújẹ́ nlá ìtàn náà kìí ṣe pé àwọn ìyókù kò kíyèsí ikú rẹ̀. Wí pé wọn kò mọ̀ pé Marinella Beretta wà ní ààyè ni ó ba ẹni ní inú jẹ́ jù lọ.”
ÒYE LÁTI INÚ ÌFỌKÀNSÌN
Ní ẹ̀yìn tí a bá rí àánú Ọlọ́run gbà, a gbọ́dọ̀ mọ àìní àwọn ẹlòmíràn. Ó rọrùn láti ṣe àìbìkítà nípa àìní àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí a jọ ń gbé, láti dákẹ́ l'órí àwọn alájọgbé àti ọ̀rẹ́ wa tí a ò rí. Ṣùgbọ́n a ń pè wá láti kíyèsí wọn.
ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ
Jésù pè wá láti kíyèsí àwọn ẹlòmíràn, láti fi àánú mọ àìní wọn. “Ní ìgbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, àánú wọn ṣe é nítorí wọ́n dà bíi àgùntàn tí kò ní olùṣọ́” (Mátíù 9:36). Èyí ni kókó inú ẹ̀kọ́ wa—ohun tí Calvin mọ̀ bíi ìbá ọmọ-ẹnìkejì wa kẹ́dùn, tàbí ohun tí a lè pè ní ìyọ́nú ní òní.
Kìí ṣe pé fifi àánú Ọlọ́run hàn yòó yọ'rí sí odò àánú níkàn, ṣùgbọ́n yòó di ibú omi ńlá tí ó ń kún àkúnya. Ní ìgbà náà ni Pétérù wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, ó bi í pé, “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí tí n yóò dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?’” (Matiu 18:21).
Ìdáríjini kìí kàn ṣe inú-rere nìkan; ìṣe ìgbàgbọ́ àti ìrètí ayéreyé ni. Ní ọ̀nà míràn, nípa nínawọ́ ìdáríjì sí àwọn ẹlòmíràn, a ń fi ìgbàgbọ́ wa hàn pé Kíríístì yòó padà wá yóò sì fi àánú mú ohun gbogbo bọ̀ sípò. Ìgbàlà wa ń jẹ́ kí a lè ko ojú oríṣi ohun ibi tí ó burú jù lọ pẹ̀lú ìrètí. “Níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá ti di púpọ̀,” bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, “oore-ọ̀fẹ́ á di púpọ̀ rékọjá” (Romu 5:20).
ÌMÚLÒ
Nítorí pé Ọlọ́run nìkan ni ó lè wo ọgbẹ́ wa sàn pátápátá kí o sì sọ òkú di ààyè, a nílò láti gba ọkàn àánú Rẹ̀ bí a yóò bá lè dáríji àwọn ẹlòmíràn. Ní ìwòye èyí ni Jésù wípé, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe” (Luku 23:34). Ǹjẹ́ ó yẹ kí a sọ nǹkan tí ó kéré sí èyí?
Jẹ́ kí a gba àdúrà kí Olúwa yí ọkàn líle àti ọkàn àìnídàáríjì wa padà. Ní gbogbo ìgbà tí a bá na ọwọ́ àánú, ìdáríjì àti ìyọ́nú ní orúkọ Jésù—ìfẹ́ tí ó dárí ẹ̀sẹ̀ elòmíràn jì—a jẹ ọlá ìjọba rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wá, ìbùkún ìjọba ọ̀run tí a ń gbádùn ní ayé ní ibí bíi ti ọ̀run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.
More