Ìjọba Àtoríkòdì: Ètò-ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Mẹ́jọ Lórí AlábùkúfúnÀpẹrẹ

Ní Ìgbà Tí Òfò bá di Èrè
Alábùkúnfún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú. Mátíù 5:4
BÍ A ṢE N BẸ̀RẸ̀
Ọ̀jọ̀gbọ́n àti onímọ̀-nípa-ti-Olórun Nicholas Wolterstorff, ní ìgbà tí ó n ṣe ọ̀fọ̀ olólùfẹ́ kan tí ó ṣe àìsí, ṣe àpèjúwe ìwòye tí ó kárí ayé nípa ìyà nínú ìwé rẹ̀, Lament for a Son: “Ìyà a máa fi ojú pa mọ́ fún ni, ní ìhà kan náà ó ṣe alábapàdé gbogbo kówá… A jẹ́ ara kan nínú ìpọ́njú. Àwọn kan jẹ́ ọlọ́rọ̀ àwọn kan orí wọ́n yá; àwọn kan lè gbé ara kébé, awon kan adùn-ífẹ́. Ṣùgbọ́n gbogbo wa ni a ń pọ́n l'ójú. Nítorí gbogbo wa ni a ń dá iye lé tí a sì ń fi ìfẹ́ hàn; pàápàá ní àkókò tí a wà l'ọ́wọ́ yìí, dídá iye lé àti fífẹ́ ni ó máa n mú ìpọ́njú wá.”
Ohun àìlèṣe-àfẹ́rí ni ìpọ́njú a máa ṣí ìlẹ̀kùn ìtùnú Ọlọ́run tí ó jú èrò ẹnikẹ́ni lọ fún ẹnìkọ̀ọ́kan wa.
ÒYE LÁTI INÚ ÌFỌKÀNSÌN
Tí a bá ń la ìgbà ọ̀fọ̀ kọjá, a lè máa là kọjá pẹ̀lú ìrúnú, tàbí àì náání ohunkóhun, tàbí ìgbàgbọ́. Ìgbà tí a bá yàn láti f'èsì pẹ̀lú ìgbàgbọ́, à n bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣe ọ̀fọ̀ ní ìgbà tí à n fi ara wa sí'lẹ̀ fún Ọlọ́run láti tù wá nínú.
ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ
Ní bíi ọgọ́rùn-ún ọdún s'ẹ́yìn, àwọn Krìstẹ́nì ti gba ara wọn ní ìyànjú láti mọ ohun tí ìyà jẹ́ kí wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bíi ìlàkọjá ayé. “Memento mori,” ni wọ́n pé é. Rántí ikú. Sùgbọ́n àkíyèsí yìí kò wọ́pọ̀ mọ́. Èyí ni àkọsílẹ̀ J.I. Packer, “Díẹ̀ nínú wa n gbé ìgbé ayé gbèrégbèré òpin ayérayé… nípa bẹ́ẹ̀ à n pàdánù.” Gbígba òkodoro yìí pé gbogbo wa ni a yíò kú ma ń fi ìtumọ̀ àti ìtara ṣàṣà kún ìrírí wa.
Ó ṣe ẹni ní àánú, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a máa ń kọ̀ láti gba òtítọ́ yìí, kí á yẹ ara wa kúrò l'ọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn ki á ma baà rí ìrora wọn kí àwọn náà sì má lè rí tiwa. Ṣùgbọ́n ìyaara-ẹni sọ́tọ̀ kò ju pé ó yà wá kúrò nínú ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́—kí a má tilẹ̀ sọ nípa ayọ̀. Bí ó ti wù kí á dá’gunlá sí ìmọ̀lára wa àti ìrora, ọkàn wa kò leè ṣe àìmọ ìkorò ní ìwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì n mí.
Kò sí ọgbọ́n tí a rí dá si ọrọ náà. Ní ìwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì ń rìn ìrìn àjò l'órí ọ̀nà gbọ́gun-gbọ̀gun, tí ó kún fún ìṣó nínú ayé ídíbàjẹ́ yìí, a yíò ṣì tún máa jẹ ìyà, a yíò sì máa ṣe ọ̀fọ̀. Ṣùgbọ́n dípò kí á máa sá kíjo kiri nínú ìdààmú, ẹ jẹ́ kí a tọ Ẹni tí Ó sun ẹkún pẹ̀lú wa, tí Ó da ara pọ̀ mọ́ wa títí dé ojú ikú ẹlẹ́yà, Ó sì n gba àdúrà fún wa ní àwọn àkókò tí ó ṣú òkùnkùn ní ọkàn wa. Ní ọ̀nà kan, ó kàn lè yé wa ní fìrìfìrì, Ọlọ́run n bá wa jẹ ìyà títí di àkókò yìí. Ǹjẹ́ kí èrò yìí ṣe ìtùnú fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe ọ̀fọ̀—kò yọ àwa náà sílè.
ÌMÚLÒ
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, èrò lásán ní ti àjálù burúkú máa ń bò wá mọ́'lẹ̀: ẹ̀rù àìsàn, àníyàn l'órí ọmọ, àdánikànwà, àjálù ètò ìnáwó, àníyàn ọjọ́ ogbó, tàbí àwọn ìrántí tí kò suwọ́n. Ní kúkúrú, a máa ń jẹ iya láti ipasẹ̀ ẹ̀rù tí kò dá ọwọ́ dúró tí wọ́n sì ń de ènìyàn mọ́'lẹ̀ dé ibi pé Krístì àti kókó iṣẹ́ ayérayé Rẹ̀ yíó fi di ohun ìgbàgbé.
Ṣùgbọ́n a kò jẹ ìyà wa ní àwa nìkan. Krístì ń gbe pẹ̀lú wa. Àwọn olùrànlọ́wọ́ a máa kùnà bẹ́ẹ̀ ni ìtura a máa sá lọ, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà títí. Ìwàláàyè tí ó ń fi ọkàn wa ṣe ibùgbé, ní àìpẹ́ yíò kárí gbogbo ayé, ìtànsán tí yíò fọ́ túútúú gbogbo òjìji agbára òkùnkùn láíláí. Ní ọjọ́ náà, “oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀.” (wo Málákì 4:2), a yíò sì sọ gbogbo ǹkan di tuntun. “Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.” (Ìfihàn 21:4). Bẹ́ẹ̀ni, “alábùkúfún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú” (Matiu 5:4).
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Nínú ìwàásù àwọn alábùkún-fún (Mátíù 5:2–12), Jésù rọ̀ wá láti ya ara wa sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ayé, nípa gbígbé ayé tí ó lòdì sí àṣà tí ó gbajúgbajà pẹ̀lú ìdánimọ̀ titun tí ó fi ìdí mú'lẹ̀ sínú rẹ̀. Ètò Ìjọba Àtoríkòdì yìí ń se àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n tí ó ta ko òye ènìyàn àti ìwúlò rẹ̀ fún òní.
More