Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 86 nínú 106

Kíni ó sọ?

Orin Dáfídì 117, a pe gbogbo ènìyàn láti yin Ọlọ́run fún ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn Rẹ̀ tó àti òtítọ́ Rẹ̀ tí kò yí padà. Orin Dáfídì 118 sọ nípa òkúta pàtàkì nínú ilé Ọlọ́run, tí àwọn ènìyàn kọ̀ silẹ, ṣùgbọ́n tí Olúwa yàn.

Kiní ó túmò sí?

Orin Dáfídì 118 je orin kan tó dá lórí Olùgbàlà èyí tó ń sọ nípa àkókò tí Jésù Kristi yóò dé, ẹni tó ṣe àpèjúwe ni pípé òtítọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run nínú Orin Dáfídì 117. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run lè yin ìfẹ́ rẹ̀ àìṣẹ̀tàn, òdodo rẹ̀, àti òtítọ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Bí Jésù Olúwa ṣe wọ Jerúsálẹ́mù lọ, ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn yìn ín, wọ́n ka Sáàmù 118:25-26" Hósánà [Gbà wá là]! Ibukún ni fún Ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa" (Máàkù 11). Lẹ́hìn náà, ní ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, ẹsẹ 23 àti 24 Jésù tọ́ka sí ara Rẹ̀ pé - Òun ní Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ sílẹ̀ tí Ọlọ́run sì yàn. Síbẹ̀-síbẹ, àwọn aṣáájú ìsìn Júù kọ̀ Jésù silẹ̀. Wọn kò mọ̀ pé àwọn ń wo Olùgbàlà àti Ọba tí wọ́n ti ń retí tipẹ́ tipẹ́" Ìfẹ́ àti òtítọ́ Ọlọ́run tí ó fara hàn nínú Ẹni tí Jésù Kristi jẹ́

Báwo ló ṣe yẹ kí n fèsì?

Ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́hìn náà, èrò àwọn ènìyàn nípa Jésù kò yí padà. Àwọn kan ti gbẹ́kẹ̀ lé É fún ìgbàlà wọn, nígbà tí àwọn mìíràn kọ̀ Ọ sílẹ̀. Inú ẹgbẹ́ wo ni ó wà? Ǹjẹ́ ìwọ náà ti ní ìrírí ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn tí Jésù Kristi bí? Báwo lo ṣe rí i tí òtítọ́ Rẹ̀ tí ó ṣe àfihàn nínú ọkàn rẹ nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ àti ẹ̀kọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́? Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́, ìfẹ́ àti òtítọ́ Ọlọ́run ń gbé inú rẹ báyìí. Wo àwọn ènìyàn lóde òní nípasẹ̀ ojú Rẹ̀. Òtítọ́ tó wà nínú Kristi nìkan ló lè dá wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ó ní ìfẹ́ tí ó jìnlẹ̀ sì wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ní ìfẹ̀ rẹ. Tani ìwọ yóò sọ fún lónìí nípa ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn Rẹ̀ àti òdodo Rẹ̀.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org