Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 85 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Àwọn òrìṣà àti-ọwọ́-ènìyàn-dá ti àwọn orìlẹ̀-èdè jẹ́ aláìlẹ́mìí, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ọ̀run ni ìrànlọ́wọ́ àti aṣà Ísírẹ́lì. Onísáàmù yin oore ọ̀fẹ́, òdodo àti àánú Ọlọ́run.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Gẹ́gẹ́ bí àṣà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ àwọn sáàmù wọ̀nyí n'ígbà Ìrékọjá. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí rán àwọn ènìyàn Ọlọ́run l'étí wí pé wọ́n yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká ní'torí pé Ọlọ́run wọn ni Ẹlẹ́dàá Ọ̀run àti Ayé. Gbogbo ògo jẹ́ Tirẹ̀ nísinsìnyí àti láéláé. Ìfẹ́ àti òdodo Rẹ̀ yẹ kí ó ti jẹ́ ìwúrí fún wọn l'áti gbẹ́kẹ̀lé E kí wọ́n sì gbọ́ràn sí I lẹ́nu pátápátá. Jésù kọ Sáàmù 116 pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ ní'gbà Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn Rẹ̀, ní'torí Ó mọ̀ pé àkókò ikú Òun ti súnmọ́ itòsi. Ó gbé "ife ìgbàlà" s'ókè, ní àkókò díẹ̀ l'ẹ́yìn náà, Ó fi oore ọ̀fẹ́ àti àánú parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán-An l'áti ṣe ní'pa ìmúratán Rẹ̀ l'áti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ayé l'órí Àgbélébùú.

Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?

Ní àwùjọ òde òní, ó dà bíi pé ìlàkàkà ń lọ kíkankíkan l'áti yọ gbogbo ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ Ọlọ́run - bí a ti fi hàn nínú Ìwé Mímọ́ - kúrò nínú ìṣèjọba, àwọn ilé ẹ̀kọ́ àti èètò ìṣèdájọ́. O kò lè yí ayé padà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lè yí ọ padà. Àwọn onígbàgbọ́ ní l'áti yàtọ̀ ní'torí wí pé Ọlọ́run wa ni Ẹlẹ́dàá, Ólùgbàlà, Olúwa, ọjọ́ kan sì ń bọ̀ tí yíò ṣe ìjọba l'órí ayé gẹ́gẹ́ bíi Ọba. Nítorí ikú, ìsìnkú, àti àjínde Krístì, o lè bọ́ l'ọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú. Àwọn ọ̀nà wo ni o ti ń fi ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbọ́ràn dáhùn sí I? Báwo ni o ṣe leè ṣe àfihàn ọpẹ́ rẹ fún oore ọ̀fẹ́, òdodo àtí àánú Rẹ̀ lónìí?

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org