Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Onísáàmù nà pe àwọn ìránsẹ́ Olúwa láti gbé ìyìn fún ẹni tí ó wà lórí ìtẹ́ gíga. Ó rántí ìjáde àwọn ọmọ Ísrẹ́lì kúrò ní Íjíbítì nígbàtí Ọlọ́run fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ìdáǹdè kúrò lóko ẹrú.
Kíni ó tún mọ̀ sí?
Orin Dáfídì 113-118, tí a mọ̀ sí orin Ìyìn ńlá(Hallelujah) ni wọ́n kọ ní àṣálẹ́ ìrékọjá. Ó dá bí ẹni pé àwọn àyọ́kà òní ni a kọ ní ìbẹ̀rẹ̀ oúńjẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Ọlọ́run ni aláàkóso ohun gbogbo tí ó wà, orin dáfídì 113 ṣe àpèjúwe ìfẹ́ àti ìlọ́wọ́sí rẹ̀ nínú ayé àwọn òtòṣì, aláìní, àti àwọn ènìyàn aláìnírètí. Nígbàtí àwọn aráa Júù kọ orin ìjáde nínú Orin Dáfídì 114, a rán wọn létí ìtúsílẹ̀, agbára àti ìpèsè rẹ̀. Èrò bí Ó ṣe wá pẹ̀lú wọn nínú ògo Rẹ̀ yóò mú ọkàn wọn wárìrì ní ìbọ̀wọ̀ fún àti ayọ̀.
Báwo ni kín ṣe dáhùn?
Ọlọ́run kìí ṣe ẹni tí ó dúró láìkópá, láìbíkítà sí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ayé. Ìlọ́wọ́síi rẹ̀ ní ìgbésí ayée wa jẹ́ ìdí tí a fi lè rántí ohun tí ó ti ṣe àtí láti yin ẹni tí ó ń ṣe. Ọlọ́run ti gbé wa kúrò nínú òṣì ti ẹ̀mí sí ipò ọlá nínúu Kristi gẹ́gẹ́ bíi onígbàgbọ́. Ó ń tọ́ wa sọ́nà nínúu ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ó sì ń pèsè fún àwọn àìní wa níti ara àti àwọn àkókò ìsọdọ̀tun ti ẹ̀mí. Ronú nípa bí Olúwa ṣe ṣiṣẹ́ ní ìgbésí ayé rẹ. Báwo ni o ṣe ní ìrírí ìtúsílẹ̀ àti agbára Ọlọ́run? Ṣíṣe ìrántí ohun tí ó ti ṣe ye kí ó mú ọ láti gbé ìyìn fún Un nígbàgbogbo àti fífi ara jìn láti gbẹ́kẹ̀le àti gbọ́ràn síi àṣẹ Rẹ̀ ójojúmọ́. Báwo ni ìgbésí ayé rẹ ṣe ma ṣe àfihàn ogún ọlọ́lá rẹ ní ọ̀sẹ̀ yí?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More