Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Dáfídì yan ìmọ̀ràn àti ìní Oluwa l'ékè àwọn ọlọ́run mìíràn.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Ní ígbà tí ó ń sá fún Sọ́ọ̀lù, Dáfídì ní àǹfààní lẹ́ẹ̀mejì l'áti gba ẹ̀mí Sọ́ọ̀lù ṣùgbọ́n ó yàn l'áti má ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ìgbà méjèèjì, Sọ́ọ̀lù sún s'ẹ́yìn fún ìgbà díẹ̀. Ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ ní àkókò ìsinmi ráńpẹ́ yìí ni Dáfídì kọ sáàmù yìí. Gẹ́gẹ́ bíi ọba tí a fi òróró yàn, Dáfídì ìbá ti gba ìtẹ́ Israẹli fún ara rẹ̀. Àwọn kan lè ti dáa l'ábàá wípé kí ó wá ìdáhùn nípa ṣíṣe ìrúbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn, ṣùgbọ́n fífi Olúwa s'ílẹ̀ yíò mú ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ síi. Dáfídì yàn l'áti tẹ̀lé òfin Olúwa, kódà n'ígbà tí ó la ìjìyà kọjá ní ìrìn àjò rẹ ṣí orí ìtẹ́. Ọlọ́run kò kọ Dáfídì s'ílẹ̀, òun náà kò sì kọ Olúwa rẹ̀ s'ílẹ̀. Ìpọ́njú jẹ́ kí Dáfídì mọ̀ pé òun kò ní ohun tí ó n'íye lórí ju Olúwa lọ.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Ìgbé-ayé kìí sábà já sí bi a ṣe ròó n'ígbà èwe wa. Ohunkóhun ló lè ṣ'ẹlẹ̀. Àwọn ètò wo ni ó ti y'ọrí ìjákulẹ̀ fún ọ? Bóyá o ní ìtẹ́lọ́rùn tàbí o kò ní ní àkókò kan níí ṣe pẹ̀lú ìwòye rẹ ju ipò tí o wà lọ. Ǹjẹ́ o gbá'jú mọ́ ohun tí Ọlọ́run kò ì tíì yàn l'áti fún ọ tàbí ò ń wo ohun tí Ó ti fi oore-ọfẹ ṣe? Ìtùnú àti agbára Olúwa nìkan ni ó mú ìtẹ́lọ́rùn tíí t'ójọ́ wá, láì bìkítà wàhálà tí ó lè yí ọ ká. Ṣé ìwọ náà yíò sọ pẹ̀lú Dáfídì pé, "Ìwọ ni Olúwa mi; láì sí Ìwọ, mi ò ní ohun kan tí ó dára"?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More