Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 13 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Dáfídì ní kí Ọlọ́run fi etí sí àdúrà rẹ̀, rí ohun tí ó tọ́, kí ó sì fi ọwọ́ Rẹ̀ gbà á là.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ pé ìgbà tí Dáfídì tún ń sá kúrò ní ọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ni ó kọ àdúrà yìí. Ó lo àwòrán ara ènìyàn l'ati ṣe àpèjúwe àwọn ìṣe ọ̀ta rẹ̀, ìdáhùn rẹ̀, àti àwọn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí Olúwa. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Dáfídì tí yíò b'ojú w'ẹ̀yìn tí Dáfídì bá fi ẹnu ṣáátá Sọ́ọ̀lù tàbí tí ó bá gb'ìyànjú l'áti gb'ẹ̀san, ṣùgbọ́n Dáfídì pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ n'ítorí pé ó pinnu l'áti tẹ̀lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wi pé ìrísí Ọlọ́run jẹ́ ohun àṣírí fún Dáfídì, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún gbogbo ènìyàn, ó ní ìdánilójú wípé Olúwa lè gbọ́ àdúrà òun, rí ohun tí ó tọ́, sọ òtítọ́, kí ó sì fi ọwọ́ Rẹ̀ gba òun là.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

L'áti ìgbà èwe, wọ́n ti sọ fún wa léraléra wípé ohun tí kò t'ọna méjì kò le pa ara pọ̀ kí wọ́n di ohun tí ó tọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa yíò gbà wípé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ n'ígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìpalára fún wa, fún ìgbà díẹ̀ ráńpẹ́ ó lè dàbìi wípé ó dára láti ṣe ìpalára sí ẹni náà padà. A lè jẹ̀bi ṣíṣe ìdájọ́ ní àdábọwọ́ ara wa dí'pò kí a fi ọkàn tán ọwọ́ Olúwa. A lo ètè wa l'áti gé wọn lu'lẹ̀ dípò títẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wá l'áti ẹnu Ọlọ́run fún'ra Rẹ̀. Ta ló ṣe ọ́ ní ìpalára gidi? Wo àdúrà Dáfídì yìí kí o sì gbàá l'ádúrà ní orí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó ṣe é ṣe l'áti wo ọgbẹ́-ọkàn sàn pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn bí a bá dúró de Ọlọ́run fún ìdáláre.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org