Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 71 nínú 106

Kí ló sọ?

Àwọn ènìyàn búburú kò ní èrò pé Ọlọ́run rí wọn, ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dà mọ àwọn èrò wọn. Òfin Olúwa ran olódodo lọ́wọ́ láti dúró, ṣùgbọ́n òun ni a ó fi ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn búburú.

Kí ló túmọ̀ sí?

Láàrin àwọn sáàmù tí wọ́n ń yin ìfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń kéde ògo Rẹ̀, ibi kíkà yìí ń pè fún ẹ̀san Rẹ̀. Òńkọ̀wé yìí tọ́ka sí ìwà aṣiwèrè àwọn tí wọ́n ń ṣe ibi sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Wọ́n ṣe bí ẹni pé Ẹlẹ́dàá jẹ́ ère aláìlẹ́mìí tí a ti ọwọ́ ènìyàn dá tí ó jẹ́ pé kò lè rí ìwà ipá wọn tàbí kí ó gbọ́ asọ̀ ìgbéraga wọn. Ní tòótọ́, kedere ni gbogbo èrò ọkàn wọn hàn sí Onídàájọ́ ayé. Ọlọ́run nìkan ni ó lè fi ìyà jẹ ẹni búburú, síbẹ̀ Ó wá àwọn tí yóo dúró lòdì sí ibi, tí wọn yóo sì kéde òdodo àti òtítọ́. Gbogbo ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò, àti gbogbo ìwà búburú ni a ó sì dájọ́ wọn nígbà tí Jésù bá padà dé.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Gbígbé nínú ayé tó ń ṣe bí ẹni pé Ọlọ́run kò sí, kò ríran, tàbí pe kò bìkítà nípa ohun tí àwọn ènìyàn ń ṣe lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹni. Kìí ṣe pé àwùjọ ń fi ójú fo ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń fi ọwọ́ sí i, ó sì tún ń yìn ín nípa fífún un ní èrè. Ìrẹ̀wẹ̀sì ti lè dé bá ọ dé ibi pé o ti ṣetán láti ya ara rẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn Onígbàgbọ́ tí ó kù bí o ṣe ń dúró de Jésu kí ó padà dé láti tún gbogbo àṣìṣe ṣe. Ṣùgbọn Ọlọ́run ń wá àwọn Onígbàgbọ́ tí wọn yó fi ìgboyà àti ìfẹ́ sọ òtítọ́ nígbà tí àsìkò ṣì wà fún àwọn ènìyàn láti yí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ibi wo nínú ayé ni ó ń bà ọ́ ní ọkàn jẹ́? Báwo ni o ṣe lè dúró lòdì sí i lónìí kí o sì kéde òtítọ́ ti Ìwé Mímọ́?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org