Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 70 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Asiwèrè kò lè mọ èrò Olúwa Ọ̀gá Ògo, ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn ń yin ìfẹ́ àti òdodo Rẹ̀. Ó ń jọba títí ayérayé nínú ọlá-ńlá, agbára àti ìwà mímọ́.

Kí ni ìtumọ̀ rẹ̀?

Bí wọ́n ti ń pèsè ọrẹ sísun ní Ọjọ́ Ìsinmi, a ń rán àwọn ènìyàn Ọlọ́run létí ọlá-ńlá àti ìjẹ́mímọ́ Rẹ̀, èyí tí ó sì jẹ́ kí wọ́n kọrin ìyìn Rẹ̀ bí ó ti yẹ, kí wọ́n kéde títóbi Rẹ̀ kí wọ́n sì ronú àwọn nnkan tí Ó ti ṣe nítorí tiwọn. Àwọn díẹ̀ lára iṣẹ́ Rẹ̀ ṣòro láti ní ìmòye wọn, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá lè ní òye Ọlọ́run ní kíkún, kì bá ti jẹ́ Ọlọ́run aláìlópin, ayérayé, alágbára-jùlọ tí wọn ń sìn. Nítorí pé àwọn ìrònú Rẹ̀ jinlẹ̀ ju tiwọn lọ, àwọn ènìyàn Ọlọ́run lè fi ìwàláàyè wọn sí ọwọ́ ìfẹ́ Rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì wo ìdúróṣinṣin Rẹ̀ bí ọjọ́ náà ti ń parí lọ.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Nígbà míràn, ọ̀nà àti ète Ọlọ́run má n fojú hàn, ìgbà míràn ẹ̀wẹ̀ a máa ń tiraka pé kí ó yé wa ni. Kí ló dé tí a fi ń sin Ọlọ́run tí a lè ní òye rẹ̀ ní kíkún? A lè fi ọkàn tán Ọlọ́run ní pípé nítorí pé èrò Rẹ̀ jinlẹ̀ àti pé ọ̀nà Rẹ̀ ga ju tiwa lọ. Bí o bá wòye bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó (Johanu 3:16), yíò di bárakú pé kí o máa fi ọjọ́ rẹ lé E lọ́wọ́ láràárọ̀. Fi ojú sọ́nà fún ọwọ́ Ọlọ́run nínú ayé rẹ lónìí kí o lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ ní ìparí ọjọ́. Yíyin òtítọ́ àti ìfẹ́ Olúwa jẹ́ jíjẹ́wọ́ sí ẹni tí Ó jẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìṣe Rẹ̀ kò yé ọ ní kíkún.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org