Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 69 nínú 106

Kíni ǹkan tó sọ?

Òní Sáàmù náà fi ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni tí ó Ga Jùlọ ṣe ibùgbé, Ó sì sinmi ní abẹ́ òjìji Olódùmarè. Ó mọ rírì Ọlọ́run ó sì ké pè ẹni tó ṣèlérí láti wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìdàrú-dàpọ̀.

Kíni èyí túmọ̀ sí?

Ọlọ́run ṣe àwọn ìlérí àrà ọ̀tọ̀ fún orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì; díẹ̀ nínú rẹ̀ sì jẹyọ nínú àyọkà ti òní. Fi ojú inú wo níní irúfẹ́ ìdáàbòbò àtọ̀runwá yìí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò sí àyè fún ìbẹ̀rù àjàkálẹ̀ àrùn, ìparun ọ̀gbẹlẹ̀, tàbí ìkọlù ọ̀tá – níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti gbọ́ràn sí Olúwa Alágbára-jùlọ lẹ́nu. Àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣe àbò lóríi wọn àfi bíi ìyẹ́ adìyẹ ti máa ń bo àwọn ọmọ rẹ̀. Olùkọ́ sáàmù yí tí a kò mọ orúkọ rẹ̀ wà ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlérí náà. Kò nílò láti sá lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tí wàhálà yọjú, nítorí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ló fi ṣe ibùgbé láti-ẹ̀yìn-wá. Ọlọ́run kò dá ọwọ́ gbogbo wàhálà rẹ̀ dúró àmọ́ Ó ṣe ìlérí láti wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú rẹ̀.

Báwo ni kí n ti fèsì?

Jésù kò fìgbà kankan ṣèlérí ìgbésí ayé ìrọ̀rùn fún àwọn ọmọ lẹ́yìn Rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ànfàní ìgbọràn wọn; kódà, ìdàkejì ni ǹkan tí ó sọ. Láti àtètèkọ́ṣe ni àwọn Kristẹni ti ń ní ìdojúkọ nípa ìgbàgbọ́ wọn nínú Kristi. Kódà lónìí, ó ṣeé ṣe kí o mọ onígbàgbọ́ olóòótọ́ kan tó ti ní àìsàn tó burú jáì tàbí tó ní ìrírí àdánù míràn. Síbẹ̀, a ní ìlérí àti ìdánilójú wípé Olúwa ń gbọ wa nígbà tí a bá gbàdúrà (1 Jòhánù 5:14-15) àti wípé Ó wà pẹ̀lú wa nínú gbogbo ìdojúkọ wa (Mátíù 28:20). Ó ṣeé ṣe fún wa láti sinmi láìní ìfòyà pẹ̀lú àlàáfíà Rẹ̀, pẹ̀lú ìdánilójú wípé ohun kan kò lè fọwọ́ kan ayé rẹ àyàfi tí Olúwa olólùfẹ́ rẹ bá gbà á láyè. Ǹjẹ́ ò ń gbé nínú Rẹ̀ lónìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org