Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 68 nínú 106

Kí ni ó sọ??

Nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ ayérayé, ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí ọjọ́ kan sí I. Mósè fẹ́ gbé ọjọ́ ayé rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n kí ó sì ní ìrírí ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ọjọ́ tí yíò gbèé.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Sáàmù 89 ni ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ Ìwé Kẹrin ti àwọn sáàmú, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu orin ayé Ísrẹ́lì nígbà tí wọ́n fi ń rìn kiri nínú aginjù. Nítorí ìṣọ̀tẹ̀ wọn, Ọlọ́run kọ̀ láti jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ti lé ní ọmọ ọdún 20 wọ Ilẹ̀ Ìlérí (Numeri 13-14). Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni a sọ di mímọ̀ níwájú Olúwa. Wọ́n ń lọ láti ibì kan dé ibòmíràn fún ọdún 40, wọn ń wò bí olúkúlùkù àgbàlagbà ṣe ń kú. Mósè fẹ́ ìrísí ayérayé Ọlọ́run lórí bí òun ṣe lè gbé ayé òun tó kù lórí ilẹ̀ ayé. Kódà rínrìnká nínú aginjù lè mú ọjọ́ ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ wá tí ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run bá ṣààmì sí wọn.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ìgbésí ayé kúrú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ rẹ̀ ni ó sì kún fún ìpèníjà, ìsòro àti ìbànújẹ́ ọkàn. Síbẹ̀síbẹ̀, o lè gbé ayé tí ó ní ìtumọ̀ tí o bá ń gbé ọjọ́ ayé rẹ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìmòye Ọlọ́run ayérayé ní ọkàn rẹ. Ó rí ayé rẹ láti ìbèrè títí dé òpin Ó sì mọ bí gbogbo ègé àdojúrú ayé rẹ ṣe lè tò papọ̀ fún ète Rẹ̀. Kò sí nnkan tí o ṣe tàbí tí o sọ tí ó pamọ́ lójúu Rẹ̀—kíka Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ń kọ́ ọ ní ọ̀nà láti gbé dáradára àti pẹ̀lú ọgbọ́n kí o ba lè gbé ayé tí ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn lójoojúmọ́. Bí o ti ń kọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, ìwọ yóò rí ìtẹ́lọ́rùn tí ó pé nínú ìfẹ́ Rẹ̀, láì ka nnkan tí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lè mú wá sí. Iye ọdún tí ó wù kí o gbé, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni ààmin wọn. Ṣé ìwọ ṣe tán láti gbé ayé dáradára pẹ̀lú ọgbọ́n lónìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org