Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 67 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Onísáàmù kọrin ìfẹ́ àti òtítọ́ Olúwa nítorí májẹ̀mú tí Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ ìran ìdílé Dáfídì. Ta ni a lè fi wé Olúwa?

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Ìgbèkùn ni Bábílónì ni onísáàmù wà nígbà tí a kọ sáàmù yí. Wọ́n ti pa Jerúsálẹ̀mù run a sì ti mú ọba ìkà rẹ̀ ní ìgbèkùn lọ. Síbẹ̀síbẹ̀ onísáàmù bẹ̀rẹ̀ nípa pípolongo ìfẹ́ àti òtítọ́ Ọlọ́run. Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú àrọ́mọdọ́mọ Dáfídì kò dá lé òtítọ́ wọn sí-I ṣùgbọ́n ó dá lé ìwa Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run. Bákan náà, ìgbàgbọ́ onísáàmù kò gbé ára lé àyídáyidà rẹ̀ ṣùgbọ́n ó fi ìdí múlẹ̀ lórí ìwà Ọlọ́run. Ọjọ́ iwájú Ísrẹ́lì kò dájú, ṣùgbọ́n wọ́n wà lábẹ́ ìtọ́jú Ọlọ́run alágbára, olódodo, olóòtítọ́ àti onífẹ̀ẹ́ wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dà bíi pé Ọlọ́run ti fa igi lé májẹ̀mú Rẹ̀, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìmúṣẹ rẹ̀ tí ó ga jùlọ ni yóò jẹ́ ìṣàkóso Jésù gẹ́gẹ́ bíi Ọba Ayérayé.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ìmọ̀lára máa ń tan ẹni; wọ́n lè mú wa láti inú ìdùnnú lọ sínú ìbànújẹ́ láàrin ìṣẹ́jú péréte, ṣùgbọ́n ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ tàbí ní àyíká rẹ kò ní nnkan ṣe pẹ̀lú ìwà àìyípadà ti Ọlọ́run. Tún Orin Dáfídì 89 wò; fa àwọn orúkọ àti ànímọ́ Ọlọ́run yọ níbẹ̀. Abala wo nínú ìwà Ọlọ́run ni ó ní ìtúmọ̀ sí ọ jùlọ lónìí? Orúkọ Rẹ̀ wo ni o ní láti pè nítorí ipò tí o wà báyìí? Rántí pé, àyídáyidà rẹ àti ìmọ̀lára rẹ lè má dúró sójú kan, ṣùgbọ́n òdodo Ọlọ́run kò yí padà.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org