Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 66 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Sáàmù 87 yin Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bíi ìlú tí Ọlọ́run fẹ́ràn. Ẹni tí ó kọ Sáàmù 88 ké pe Ọlọ́run pé kí Ó gbà á lọ́wọ́ àìsàn tó fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Àwọn sáàmù wọ̀nyí yàtọ̀ pátápátá sí ara wọn. Sáàmù àkọ́kọ́ fi tayọ̀tayọ̀ sọ pé Jerúsálẹ́mù ni olú ìlú ayé, ó sì jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn tí wọ́n bí níbẹ̀ fi ń yangàn, àwọn kan sì sọ pé sáàmù 88 ni sáàmù tí ó ń bani nínú jẹ́ jù lọ. Ẹsẹ tó gbẹ̀yìn orí kọ̀ọ̀kan ni ó jẹ́ kí a mọ̀ ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín wọn. Sáàmù 87 parí pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi orísun ayọ̀ onísáàmù náà, Sáàmù 88 sì parí pẹ̀lú òkùnkùn gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rẹ́ onísáàmù náà. Ó dà bíi pé àìsàn kan tí ó lè gbẹ̀mí rẹ̀ ti bá a fínra ní èyí tí ó pọ̀ jùú lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, bóyá àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ nínú Ẹni Gíga Jù Lọ, Ẹni tí Ó dá Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, ni ìpìlẹ̀ àdúrà rẹ̀.

Bawo ló ṣe yẹ kín dáhùn?

Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi náà máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tí ó pọ̀ gan-an. Àìsàn tí ó lè gbẹ̀mí ènìyàn, ikú ọmọ, àti àìrí iṣẹ́ ṣe fún àkókò gígùn máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ó jẹ́ onígbàgbọ́ àti àwọn tí kìí ṣe onígbàgbọ́. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwọn sáàmù tí a kà ní òní ṣe rí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe yẹ kí ìyàtọ̀ wà nínú ọ̀nà tí Kristẹni kan gbà ń kojú ìjìyà yàtọ̀ síra. Ǹjẹ́ o ní ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ tí ó ń mú ọ kúnlẹ̀ níwájú Olúwa? Dúró nísinsìnyí, kí o sì bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ láì fi ọ̀rọ̀ sí ábẹ́ ahọ́n sọ nípa ipò yòówù kí ó má kó ìdààmú bá ọ. Kódà nígbà tí ó jẹ́ pé òkùnkùn nìkan lo rí, Olúwa lè jẹ́ ìrètí àti orísun ìdùnnú rẹ.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org