Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Dáfídì ké pe Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà àti àánú nígbà tí ó ń yin oore Ọlọ́run àti ìfẹ́ tí kì í kùnà.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Orin Dáfídì yìí gbé ìwà Dáfídì láàrin ọgbẹ àti ìyìn rẹ̀ yẹ̀wò. Àwọn ìdí tí ìbànújẹ́ rẹ̀ jẹ́ ìpọ́njú ára, rìkìsí tí ó lòdì sí ayé rẹ̀, àti ìdàlẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Pẹ̀lú ìdí fún àníyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ apá ìgbésí ayé, ẹ̀dùn ọkàn pọ̀ fún Dáfídì. Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbẹ́kẹ̀lé tí Dáfídì ní nínú Olúwa bo àwọn àníyàn onígbà díẹ̀ ayé rẹ̀. Nígbà tí Dáfídì fi ìmọ̀lára rẹ̀ lé lẹ̀ fún Ọlọ́run olóòótọ́, ó ní ìrètí ní ọ̀tun.
Báwo ni ó yẹ kí n ṣe dáhùn?
Ní ààyè kan, o lè ti lo ọ̀rọ̀ yìí, "Nígbàtí òjò bá rọ̀, ó máa dà sílẹ̀," láti ṣe àpèjúwe àwọn ìdí tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi wà nínú ìgbésí ayé rẹ. Nígbàtí ìṣòro kan tàbí òmíràn bá n gun orí ara wọn, ìmọ̀lára rẹ má dàrú, èyí tí ó máa mú kí o tètè bínú. Nígbà tí Ọlọ́run dá wa pẹ̀lú ìmọ̀lára, kò túmọ̀ sí pé kí ìmọ̀lára wa máa darí wa. Àwọn ìmọ̀lára wo ni o nílò láti jọ̀wọ́ fún Olúwa ní báyìí - àníyàn, ìbínú, ìbẹ̀rù, owú? Gbígbé ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lé Olùwà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ ní ipò kọ̀ọ̀kan yóò mú ọ kúrò ni ipò ìmọ̀lára tí n Iọ sókè-sọ́dọ̀, yóò sì mú ọ rinlẹ̀ nínú ìrètí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More