Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kínni ó sọ?
Ọlọ́run ran Dáfídì lọ́wọ́ nígbà tí ó pè é fún ìrànlọ́wọ́. Ẹkún rẹ̀ di ijó, ọ̀fọ̀ rẹ̀ sì yí padà sí ayọ̀ kí ó lè kọrin ìyìn sí Ọlọ́run kí ó sì máa dúpẹ́ títí láé.
Kínni ó túmọ̀ sí?
Ó hàn gbangba pé, Dáfídì ti ní ìrírí ìbáwí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àìsàn ara tó pọ̀, bóyá lẹ́hìn ìgbà tí ó ṣẹ̀ nípa kíka àwọn ènìyàn (Kronika Kinni 21) - bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kò dá wa lójú. Nígbà tí Dáfídì fi ìrẹ̀lẹ̀ béèrè fún àánú, Olúwa dárí jì í, ó sì mú ìlera rẹ̀ bọ̀ sípò. Ipa ìdáríjì tí ó rí jẹ́ òdì kejì kí ó gba ẹ̀ṣẹ̀ láàyè nínú ayé rẹ̀; ayọ̀ rọ́pò ẹkún, ọ̀fọ̀ yí padà sí orin ìyìn. Dáfídì kò lè dákẹ́ láì sọ nípa àánú àti òdodo Ọlọ́run.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, a máa ń pàdánù àwọn ànfàní láti jẹ́ ẹlẹ́rìí oore Ọlọ́run nítorí ṣíṣe bẹ yóò túmọ̀ sí ṣíṣe àfihàn ohun kan nínú ayé wa ìgbà kan tí ó mú ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìtìjú lọ́wọ́. Ronú nípa àkókò kan nígbà tí ìṣòtítọ́ Ọlọ́run hàn gbangba lákòókò tí òkùnkùn bo ayé rẹ. Bóyá oko òwò fi orí ṣánpọ́n, ọmọ ṣe aláìsí, àbí o ṣe aṣemáṣe. Báwo ni o ṣe rí I tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn àyídáyidà yí àti nínú ọkàn rẹ? Ó dára láti yin Ọlọ́run ní ìkọ̀kọ̀, ṣùgbọ́n ní ìgbà míràn Ó fẹ́ kí á sọ̀rọ̀ nípa bí ó ti ṣiṣẹ́ nínú ayè wa ní gbangba. Dúró báyìí kí o yin Ọlọ́run fún ohun tí Ó ti ṣe fún ọ, lẹ́hìn náà, wá ààyè láti sọ fún ẹlòmíràn. Ṣé ìwọ yó fi òpin sí ìpalọ́lọ́ rẹ lónìí?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More