Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 22 nínú 106

Kíni ó sọ?

Ẹ fún Olúwa ní ògo tí ó yẹ orúkọ Rẹ̀, kí ẹ sì máa jọ́sìn fún nínú ẹwà ìwà mímọ Rẹ̀. Ó ti gorí ìtẹ́ títí láé gẹ́gẹ́ bí Ọba, ó ń fún àwọn èniyàn Rẹ̀ lókun àti àlàáfíà.

Kí ló túmọ̀ sí?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Dáfídì rí ìjì líle tó ń sán láti òkun ló tó kọ orin yì. Ààrá àti mànàmáná náà fi ògo Ọlọ́run hàn, èyí sì mú kí Dáfídì dúró láti jọ́sìn Aṣẹ̀dá lákókò tí ìjì apanirun ń jà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un nígbà tí ẹ̀fúùfù àti òjò náà rọlẹ̀ níkẹyìn. Ọlọ́run kan náà tó ṣàkóso ìkún omi ńlá ní ọjọ́ Nóà ló dá ìjì yì. Dáfídì ní ìbàlẹ̀ ọkàn nígbà tí ìjì ń jà ní ìgbqésí ayé rẹ̀, ó sì ní okun láti sin Ọlọ́run tó ń ṣàkóso ohun gbogbo.

Báwo ní kí ń ṣe dáhùn?

Àìmọye ọ̀nà ni a fí fún wa láti máa yin Ọlọ́run ká sì máa jọ́sìn fún un lódindi ọjọ́. Agbára àti ọlá ńlá rẹ̀ hàn kedere nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan tó dá, ó sì ń jẹ́ ká rí bí Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ – gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ṣe rí nínú ìjì. Kini o ṣe máa ń rí àwọn ǹkan tí Ọlọ́run dá nínú ilé rẹ, níbi iṣẹ́ tàbí ní ojú fèrèsé ilé ẹ̀kọ́ rẹ loni? Àwọn èròjà ìwà Rẹ̀ wo ló mú ọ rántí láti máa yìn ín? A lè rí ìtùnú, okun, àti àlàáfíà nínú pé Ọlọ́run kan náà tí à ń sìn ni ẹni tó dá àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú ayé, tó sì tún ń ṣàkóso wọn. Báwo lo ṣe máa jọ́sìn fún Ọba náà lónì?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org