Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 21 nínú 106

Kíni ohun tí ó sọ?

Dáfídì wá ojú Ọlọ́run, ó béèrè pé kí Ó máṣe dákẹ́ mọ́, lẹ́yìn náà ó dúró. Ẹ̀rù kò bàá nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé lé Ọlọ́run bíi ìmọ́lẹ̀, ìgbàlà, apata, àti odi mi.

Kíni ó túmọ̀sí?

Dáfídì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú ewu pípàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ogunlọ́gọ̀ ọ̀tá, nínú èyítí ó pẹ̀lú àwọn ará ilé rẹ̀. Ìpayà à ún gbé nínú irú ewu báyìí léraléra lè ti mú ìrẹ̀wẹ̀sì dé ní àwọn ìgbà kan. Nígbàtí ayé bá dàbíi ilẹ̀ tí kò mọ́ mọ́, Dáfídì wá ojú ati ohùn Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Ọlọ́run tú gbogbo ẹ̀rù Dáfídì ká nípa títàn ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn àti pẹ̀lú fífi okun fún Dáfídì láti dúró. Ibi yòówù tí ó lè ma sápamọ́ sí, ibi ìṣó àti ìgboyà fún Dáfídì ni iwájú Olúwa, Apata rẹ̀, àti odi rẹ̀.

Báwo ni kí ń ṣe fèsì?

Àwọn ọmọdé tí ẹ̀rù òkùnkùn ńbà a máa wá ìtùnú lọ sórí ibùsùn àwọn òbí wọn ní ọ̀ganjọ́ òru. Ojú àti ohùn àwọn tí ó fẹ́ràn wọn jùlọ yìí a máa lé ẹ̀rù wọn lọ. Kíni ohun tí ó ún dá ẹ̀rù bà ọ? Tani o ún sábá nígbàtí òkùnkùn tó ṣú dàbíi aláìlópin? Iwájú Ọlọ́run Bàbá kò ju pípè lóhùn kẹ́lẹ́ lọ. Ohùn Rẹ̀ já gaara jáde láti ojú Ìwé Mímọ́, àti ìtùnú tí ó ún bẹ níwájú Rẹ̀ ní a lè mọ̀ dájú nígbàtí o bá gbàdúrà. Ọlọ́run Yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ, àgbàrá, ààbò, ìrànwọ́, àti odi ipò yòówù tí ó ún là kọjá lónìí. Ǹjẹ́ oó yípadà Síi pẹ̀lú ẹ̀rù rẹ̀ ní báyìí?

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org