Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 20 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Dáfídì jẹ kí ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìrètí rẹ̀ dúró ṣinṣin nínú Olúwa ní gbogbo ìgbà nígbà tí ìṣòro àti ọ̀tá rẹ̀ bá pọ̀ sí i.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tinilójú tí ó ṣe okùnfà bí Dáfídì ṣe kọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orin wọ̀nyí jẹ́ elénìní tí Absalomu ọmọ rẹ̀ jẹ́ fún (Orin Dáfídì25) àti ìyàn tàbí àjàkálẹ̀ àrùn (Orin Dafidi 26). Àwọn ńkan tí Dáfídì ǹ béèrè lọ́wọ́ Ọlọ̀run ati bí ó ṣe tán awọn ìṣòro rẹ ṣe àfihàn igbesi ayé ìdúróṣinṣin, igbagbọ ti o ni ìgbẹ́kẹ̀lé, àti Olúwa tí ó nifẹ tí ó sì ṣe é fọkàn tán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìdáláre, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àdúrà wọ̀nyí dá lórí ìfẹ́ Dáfídì láti dúró déédéé níwájú Olúwa nígbà tí ó ń dúró de ìgbésẹ̀ tí Òun yíò gbé. Ó lè gbóríyìn fún Olúwa ní gbangba ìta kí ó sì dúró lórí àrólé tó lágbára pẹ̀lú àwọn ipòkipò tí ó wà nítorí pé ó kọ́kọ́ bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ pé, "Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kọ́ mi ní ipa ọ̀nà rẹ, kí ó sì tọ́ mi sọ́nà òtítọ́."

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Báwo ni o ṣe ń gbàdúrà nígbà tí ìṣòro bá dé bá ọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹlòmíràn dá? Báwo ni àkókò tí àyànmọ́ bá fa ìṣòro tí ó tayọ oye ẹnikẹ́ni bá dé bá ènìyàn? Bí àwọn ìpèníjà ṣe ń wáyé ní ọ̀sẹ̀ yí, kọ́kọ́ gbàdúrà nípa ìgbésẹ̀ tí ìwọ fúnra rẹ yíò gbé nípa ọ̀rọ̀ náà. Béèrè lọ́wọ́ Ọlọ̀run lati fi awọn ọna Rẹ̀ han ọ, kí ó kọ ọ ní awọn ipa-ọna Rẹ, ki o si ṣe itọsọna òtítọ́ fun ọ - kí ó tó gbé ojú lè awọn agbara rẹ ati àwọn ẹ̀dùn rẹ lórí ènìyàn tabi ìṣòro naa. Òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ní ayé yí bí ìpèníjà kan tí ń níyànjú ní òmíràn ń dúró de ọ. Ohun tí ó ṣì wà ní gbogbo ìgbà tí kò yí padà tí a nílò ni ìtọ́ni àti ìjúwe ọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ní ọsẹ yí, kini adura ìgbésí ayé rẹ yíò ṣé ṣe àfihàn rẹ̀, nípa ìgbé ayé rẹ, ìgbàgbọ́ rẹ, ati Olúwa rẹ pẹ̀lú?

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org