Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Ísráẹ́lì gba àdúrà pé kí àwọn ọmọ ogun wọn ṣe àṣeyọrí. Dáfídì sì yọ̀ nínú àwọn ìṣẹ́gun, ìbùkún, ìwàláàyè, àti ìfẹ́ Olúwa bí ó ṣe ń kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run n'ítorí Ó fún wọn ní agbára.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Kí Dáfídì tó ṣáájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí ojú ogun, ó ṣáájú wọn nínú àdúrà. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe àfihàn bí ó ṣe fi ojú ẹ̀mí wo ogun tí ó d'ojú kọ ọ́. Ó fí òyé gbà pé àsìhá tí ń fẹ́ ní iwájú àwọn ọmọ ogun Ísráẹ́lì kò dúró fún títóbi òun ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run wọn. Ànfààní tí wọ́n ní ní ojú ogun ni wọ́n so pọ̀ tààrà pẹ̀lú orúkọ Olúwa, kìí ṣe iye ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ó jáde. A san ẹ̀san ìgbàgbọ́ Dáfídì pẹ̀lu ààbò ìwàláàyè Ọlọ́run, a sì gbé Olúwa ga, ní Ísráẹ́lì àti ní áàrin àwọn ọ̀ta wọn.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Àwọn ìpèníjà ayé fi ara pẹ́ ogun. N'ígbà míràn o lè dà bí í ẹnipé ò ń ja ogun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Kristi, a máa ń rò pé ó yẹ kí Ọlọ́run wà ní ìhà wa, kí Ó sì máa ràn wá l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àṣeyọrí. Àmọ́ ìbéèrè pàtàkì ni bóyá a wà ní ìhà Rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Bí o bá fẹ́ kí àwọn èròǹgbà rẹ y'ọri sí rere, o ní láti jẹ́ kí àwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ ṣe déédé pẹ̀lú ti Ọlọ́run. Òun yíò ṣe àtìlẹ́yìn ní gbogbo ìgbà fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lẹ́ orúkọ Rẹ̀ tí wọ́n sì dúró ṣinṣin l'órí Ọ̀rọ Rẹ̀. Ohun kejì ni bóyá ò ń ja ogun náà nínú ara nìkan. Ro'nú n'ípa ìpèníjà tí ó ń d'ojú kọ lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí ní àìpẹ́ yìí. Ǹjẹ́ o gba àdúrà rárá? Ṣé ohun tí ó jẹ ọ́ ní ogun ni bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kàn ọ́ tàbí bí a ṣe lè bu ọlá fún Ọlọ́run n'ípasẹ̀ rẹ̀? Kí o tó d'ojú kọ ìṣòro tí ó kàn, rántí pé bíborí ogun bẹ̀rẹ̀ n'ípa wíwọ́lẹ̀ l'órí eékún rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More