Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 17 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Dáfídì k'ígbe sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò ní ọwọ́ àwọn èniyàn búburú, ó sì yìn-Ín fún ìdáhùn. Àwọn ìran tí ó ń bọ̀ ní ọjọ́ iwájú yíò yin Olúwa, wọn yíò sì kéde òdodo Rẹ̀

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Sáàmù 22 ni àkọ́kọ́ nínú àwọn "Orin Olùṣọ́-Àgùntàn" mẹ́ta tí ó ṣe àpèjúwe iṣẹ́-ìránṣẹ́ Jésù ní ayé. N'ígbà tí ó ń gba àdúrà nípa ìjìyà tirẹ̀, Dáfídì ṣe àpèjúwe àgbélèbú, àjíǹde, àti ìjọba Kristi ní ọ́jọ́ iwájú. Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ní ẹsẹ 18 l'áti ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣe pàtàkì bí a ṣe ń sọ ọ́ nínú gbogbo Ìhìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin (Mátíù 27:35; Máàkù 15:24; Lúùkù 23:34; Jòhánù 19:23-24). Àwọn ẹsẹ̀ márùn-ún tí ó kẹ́yìn ti ṣẹ, ó ṣì ń ṣẹ, yíò sì tún ṣẹ, nítorí ìran kọ̀ọ̀kan níílò l'àti gbọ́ wípé Olùṣọ́-àgùntàn Rere fi ẹ̀mi Rẹ̀ fún àwọn àgùntàn Rẹ̀ (Jòhánù 10:11).

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Bí o ṣe ń ka àyọkà yìí, ṣé o ro'nú nípa bí o ti ṣe jẹ́ ara ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀? Ní àkókò kan, o wà l'ára "àwọn ìran ọjọ́ iwájú [tí a] sọ fún nípa Olúwa." Báwo ni o ṣe dáhùn sí ìròyìn pé Olùṣọ́-Àgùntàn Rere fi ẹ̀mí Rẹ̀ fún ọ? Bí o bá ti yàn l'ati tẹ̀lé E, n'ígbà náà ni ipa tìrẹ nínú àyọkà àsọtẹ́lẹ̀ yíí tẹ̀síwájú ní ẹsẹ̀ 31, "‭‭‬‬Kéde ìgbàlà Rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí." Ojúṣe gbogbo ìran onígbàgbọ́ ni láti sọ ìtàn Jésù fún ìran tí ó ń bọ̀. Báwo ni o ṣe máa fínnú-fíndọ̀ kéde orúkọ Olúwa lónìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org