Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run fi ẹni tí Ó jẹ́ hàn, àṣẹ Rẹ̀ sì ń san èrè fún àwọn tí ó tẹ̀lé wọn. Ìfòyemọ̀ Rẹ̀ ń ṣ'àfihàn ẹ̀ṣẹ̀ kí ẹnikẹ́ni má bàá lè jẹ́ aláìlẹ́bi l'ójú Rẹ̀.
Kí ni ìtumọ̀ rẹ́?
Sáàmù yìí fi ìdí tí Dáfídì fi tẹ̀lé Olúwa hàn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwòye tí ó tọ́ nípa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹni tí ó dá gbogbo nkan n'ígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àdúgbò ń sin ẹ̀dá oríṣiríṣi. Dáfídì tún rí àwọn àǹfààní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí ó wà nínú títẹ̀lé Òfin Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí ó ti ń gbé ní ọ̀dọ̀ Saulu kọ́ ọ pé ìgbọràn sí Olúwa mú ìtẹ́lọ́rùn wá ju ọrọ̀ tàbí ọlá ààfin lọ. Ní ìkẹyìn, Dáfídì gbádùn ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Olúwa. Ó mọ̀ wí pé òun f'ọ́jú sí àwọn àṣìṣe tí Ọlọ́run nìkan lè fi hàn-án. Ìrònú déédéé l'órí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàn ìmọ́lẹ̀ sí àwọn ibi òkùnkùn ọkàn rẹ̀, tí ó ń jẹ́ kí ó mọ ohunkóhun tí yíò mú inú Olúwa dùn.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
A sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe fi ara Rẹ̀ hàn nínú Ìwé Mímọ́. Kí ló dé tí èyí fi ṣe pàtàkì? Èrò tí ó tọ́ nípa Ọlọ́run ṣe pàtàkì láti leè ní èrò tí ó tọ́ nípa ara rẹ. Fún àpẹẹrẹ, gbígba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá alágbára ń ràn wá l'ọ́wọ́ l'áti mọ àṣẹ Rẹ̀ wí pé Ó retí ìgbọràn wa pátápátá sí àwọn ọ̀nà Rẹ̀. Àwọn ìgbàgbọ́ wo nípa Olúwa ni o ti pàdé l'ẹ́nu àìpẹ́ yìí? Bàwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi ìdí àwọn ìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn mú lẹ̀ tàbí ta kò ó? Tí o bá bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní ójoojúmọ́ l'áti kọ́ ẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí o sì ń yin orúkọ Rẹ̀ l'ógo nínú àdúrà, ó ṣe é ṣe kí èrò àti ìṣe rẹ ní gbogbo ọjọ́ náà tẹ́ Ẹ lọ́rùn ní àkọ́kọ́ àti ní ìṣáájú.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More