Ẹ fi iyìn fun Oluwa: nitori ohun rere ni lati ma kọ orin iyìn si Ọlọrun wa: nitori ti o dùn, iyìn si yẹ. Oluwa li o kọ́ Jerusalemu: on li o kó awọn ifọnkalẹ Israeli jọ. O mu awọn onirora aiya lara da: o di ọgbẹ wọn: O ka iye awọn ìrawọ; o si sọ gbogbo wọn li orukọ. Oluwa wa tobi, ati alagbara nla: oye rẹ̀ kò li opin. Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ. Ẹ fi ọpẹ kọrin si Oluwa; kọrin iyìn si Ọlọrun wa lara duru: Ẹniti o fi awọsanma bò oju ọrun, ẹniti o pèse òjo fun ilẹ, ti o mu koriko dàgba lori awọn òke nla. O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwò ti ndún. Kò ṣe inudidùn si agbara ẹṣin: kò ṣe inudidùn si ẹsẹ ọkunrin. Oluwa nṣe inudidùn si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀. Yìn Oluwa, iwọ Jerusalemu; yìn Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni. Nitori ti o ti mu ọpá-idabu ẹnu-bode rẹ le; o ti busi i fun awọn ọmọ rẹ ninu rẹ. O fi alafia ṣe àgbegbe rẹ, o si fi alikama didara-jù kún ọ. O rán aṣẹ rẹ̀ jade wá si aiye; ọ̀rọ rẹ̀ sure tete. O fi òjo-didì funni bi irun-agutan, o si fún ìri-didì ká bi ẽrú. O dà omi didì rẹ̀ bi òkele; tali o le duro niwaju otutu rẹ̀. O rán ọ̀rọ rẹ̀ jade, o si mu wọn yọ́; o mu afẹfẹ rẹ̀ fẹ, omi si nṣàn. O fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn fun Jakobu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Israeli. Kò ba orilẹ-ède kan ṣe bẹ̃ ri; bi o si ṣe ti idajọ rẹ̀ ni, nwọn kò mọ̀ wọn. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
Kà O. Daf 147
Feti si O. Daf 147
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 147:1-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò