Joẹli Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé Wòlíì Joẹli
Joẹli ọmọ Petueli ti fi ìgbà kan wà ní àárín àwọn ènìyàn Israẹli. Ó mọ àìṣedéédéé wọn, ó sì mọ àìdọ́gba wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Juda ṣẹ̀ nípa sí sin òrìṣà. Ó pè wọ́n kí wọ́n padà tọ Ọlọ́run lọ, kí wọn má ba à ní ìpín nínú ìjìyà ìdájọ́ tí ń bọ̀, kí wọn kí ó sì lè gbà ìbùkún tó ń bọ̀ lẹ́yìn ìdájọ́.
Joẹli rí ogunlọ́gọ̀ eṣú tí ó bo ilẹ̀ àti àìrọ̀ òjò tó sọ Juda di ahoro. Eṣú tí Joẹli ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́ eṣú gidi kì í ṣe ìṣígun àti ìgbógunti àwọn Babeli, Medo-Pasia, Giriki àti Romu bí àwọn kan ṣe túmọ̀ rẹ̀. Nínú ìdojúkọ yìí ni ó ti pè fún ìrònúpìwàdà gbogbo ènìyàn: ọmọdé àti àgbàlagbà (1.2-3) ọ̀mùtí (1.5), àgbẹ̀ (1.11), àti àwọn àlùfáà (1.13). Ó ṣàpèjúwe eṣú yìí bí ọmọ-ogun Olúwa, ó sì sọ nípa bíbọ̀ wọn bí ohun tó ń rán ni létí pé ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé. Ọjọ́ Olúwa yóò jẹ́ ọjọ́ ìtúsílẹ̀ àti ìbùkún fún Israẹli lẹ́yìn ìdájọ́ àti ìrònúpìwàdà.
Kókó-ọ̀rọ̀
Ìpè fún ìṣọ̀fọ̀ àti àdúrà 1.1–2.11.
Ìpè fún ìrònúpìwàdà àti àdúrà 2.12-17.
Olúwa ra Juda padà 2.18-27.
Olúwa sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ di ọ̀tun 2.28-32.
Ìdájọ́ orílẹ̀-èdè àti ìbùkún àwọn ènìyàn Ọlọ́run 3.1–3.21.
ទើបបានជ្រើសរើសហើយ៖
Joẹli Ìfáàrà: BMYO
គំនូសចំណាំ
ចែករំលែក
ចម្លង

ចង់ឱ្យគំនូសពណ៌ដែលបានរក្សាទុករបស់អ្នក មាននៅលើគ្រប់ឧបករណ៍ទាំងអស់មែនទេ? ចុះឈ្មោះប្រើ ឬចុះឈ្មោះចូល
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
Used by permission of Biblica, Inc. All rights reserved worldwide.