1
Mika 4:5
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
YCB
Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ OLúWA. Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
ប្រៀបធៀប
រុករក Mika 4:5
2
Mika 4:2
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLúWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ OLúWA láti Jerusalẹmu.
រុករក Mika 4:2
3
Mika 4:1
Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé OLúWA lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.
រុករក Mika 4:1
4
Mika 4:3
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
រុករក Mika 4:3
គេហ៍
ព្រះគម្ពីរ
គម្រោងអាន
វីដេអូ