Wíwá Àlàáfíà Nínú ÌdúróÀpẹrẹ

Ojó Kẹfà: Ìrọ̀ Inú Olórun
“Èmí mọ̀ pé ìwó lè ṣe ohun gbogbo, àti pé, kòsí ìrọ̀ inú tí a lè fàséhìn kúrò lódò rè” Jobu 42:2
Ìtàn ìgbésí ayé Jobu máa ń sáábà fún mí ní ìpọ̀rúru ọkàn. Báwo ní ènìyàn yíò ṣe pàdánù ohun tí ó pò tó béè gé tí tí yíò sì tún dúró ní tòótọ pèlú ìgbàgbọ́ nínú Olórun. Joobu mo ohun kan tí òpòlopọ̀ onígbàgbó òde òní kò mọ̀.
Jobu ní ìmọ̀ nípa Olórun gidi, àti ní ọ̀nà míràn Jobu mọ̀ nípa àgbàrá, ogbón àti àṣẹ tí Olórun ní láti ṣe ohun tí ó bá fé. Nínú ibi kíkà wa tí òní, Jobu ńrán wá létí pé ohunkóhun tàbí enikéni kọ̀ lè dá ìrọ̀ inú Olórun dúró àtipé kòsí ohunkóhun tí ó ṣòro fún Olórun láti ṣe, tíì kò bá tíì ṣeé ọ wà nínú ìró inú rè síbè.
Ohunkóhun tí ó bá gbà láàyè láti wo inú ayé wa, ó jé ìrọ̀ inú tí ó mọ̀ bí yíò sì jé fún rere wa. Ìfọ̀kànbalè wá gbọdọ̀ wà nínú ohun tí ó leè ṣe láti mú ohun gbogbo dára ní àsìkò tirẹ̀.
Bákannáà gégébí óti rí nínú òro Jobu tí kò sí ààyè fún láti ṣe àwárí kankan. Báwo lo séń ṣe nígbàtí ọ kò mọ ohun tíó selè? Ǹ jé ọ̀ń dúró ní tòótọ? Gégébí ènìyàn a máa ń rọ̀ wípé àwa ní óye jùlo fún ohun kan ju àwọn ẹlòmíràn lo, sùgbón ìgbéraga ní èyí. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń mú àánú Olórun wá, àti pé ìbùkún Olórun kìí ṣe ohun tí a ní ètó sí sùgbón ànfààní ni'o jé fún wá nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ rẹ.
Esè ìrántí pé Olórun ko ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ó sì ń fí oore ọ̀fẹ́ fún àwọn òní ìrẹ̀lẹ̀.
Àròjinlẹ̀:
Irú èkó tàbí òtító wo ni Olórun fé kí ọ kó láti ara rè tàbí ara re ní irú àkókò tí ọ wà yìí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ní ìgbà kan tàbí òmíràn, gbogbo ènìyàn gbódò ní ifòrítì ní àsìkò ìdúró. Ní ìgbà àti àsìkò tí mo wà nínú ìdúró,mo se àwárí agbára tí ó wà nínú òrò Olórun àti àwọn ẹrí ti ó runi sókè láti ẹnu àwọn ènìyàn kan láti gbé ìgbàgbọ́ mi ró ṣinṣin. É dara pò pèlú mí nínú ìrìn àjò olójó méje níbi tí aó ti fi agbára tí ó wà nínú dídúró ní idakẹrọrọ àti ìrètí fara mọ àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Olórun tí kìí yẹ̀ lái nípa ìlérí rè. Ẹjé kí á gba agbára àti ìtùnú láti inú òrò Olórun.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Omoyemi Ojo fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: mywaitingroom.co.uk









