Wíwá Àlàáfíà Nínú ÌdúróÀpẹrẹ

Ojó Karùn-ún: Àbò Olórun
Ǹjé ọ ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kò tíì fún ọ ní ohun tí ọ̀ń fé láti odún díè séyìn? Ronú rẹ padà séyìn. Mo ní ìrètí ní ìgbà kan láti rí isé ní agbègbè kan pàtó, nítorí mó lérò wípé èyí ni ìpinnu tí ó dára jù, láì mò wípé pánpé ní ó jé fún mi pèlú àwọn ìlànà àti àdéhùn tíó yàtọ̀ sí èyí tí a ṣe àfihàn rè. Olórun ṣeun wípé mí ọ̀ rí isé náà gbà, kàkà bẹ́ẹ̀, Olórun fún mi ní ohun tó dára jù èyí lo ní agbègbè tí ó dára jù.
Mo rántí ní ìgbà kan tí mọ̀ń retí àṣeyọrí àjosepọ̀ ìfé kan. Ówù mí tókàn tókàn láti wà pèlú eni yìí, tí mo ṣì lérò pé mo ti mọ ohun tí ìfé túnmọ̀ sí. Ó wọ̀mílórùn nítorí ọmọkùnrin yìí ńfé ìgbéyàwó ní kíákíá, sùgbón mo mọ̀ wípé èmi ọ̀ tíì ṣe tán. Kò pé sí ìgbà yìí tí a pín yà, ọkàn mí dàrú láì mò wípé ìbùkún ni fún mi. Mo ti wá ṣe ìgbéyàwó pèlú ọkùnrin tí ó fí sùúrù dúró dẹ̀ mí tíó ńfi sùúrù bámi gbé pàápàá jùlo nínú ìgbéyàwó wa.
Ní òpò ìgbà, ìdádúró kìí ṣe pé kòní ṣeéṣe, sùgbón àbò kúrò l'ówó èṣù. Olórun pinnu láti dáàbò bò wá kìíse láti fún wa láàyò nìkan. Gégébí ìyá kò lè fún ọmọ rẹ ní iná láti fi ṣe eré nítorí ón su'kún kí ó wàá lérò wípé yíò mú inú rè dùn, nítorí pé iná náà yóò jọọ lówó.
Bákan náà, bàbá wa tín be l'órun kìí gbó gbogbo igbe láti fún ọ ní ohun tí ọ̀ń fé, nítorí isé rè àkókó ni láti dá àbò bò ó lówó ewu.
Àdúrà tí ó léwu tí ó sì lágbára jù nipé “Olórun jé kí ìfé rẹ kí ó ṣe”. Jésù nínú ọgbà gestimani kò fé la ìrora àti ìjìyà ikú fún ọmọ ènìyàn kọjá síbè ọ gbàdúrà wípé kíì se ìfé mi sùgbón ìfé Olórun ni kí ó ṣe (Luku22:42). Tí ọ bá gbá ìfé Olórun láàyè ìwo yóò ní ìrírí isé Jésù tíó dára jùlo. Lóòtó ó rọrùn láti só ju láti ṣe lo, sùgbón ó jé ohun tí a gbódọ̀ máa ṣe ní ojoojúmo, láti máa fo jú fo ìfé tiwa, kí á sì máa jékí ìfé Olórun kí ó ṣe.
Àròjinlẹ̀:
Sé olè gbà àdúrà yìí tọkàntọkàn pẹ̀lú ìgbàgbọ́; kìí ṣe ìfé tèmi bíkọ̀ ṣe ìfé tìre Olórun? Tí ìdáhùn rẹ bá jé béè kò, fí ọkàn wa ìdí tí ó fí rí béè.
Nípa Ìpèsè yìí

Ní ìgbà kan tàbí òmíràn, gbogbo ènìyàn gbódò ní ifòrítì ní àsìkò ìdúró. Ní ìgbà àti àsìkò tí mo wà nínú ìdúró,mo se àwárí agbára tí ó wà nínú òrò Olórun àti àwọn ẹrí ti ó runi sókè láti ẹnu àwọn ènìyàn kan láti gbé ìgbàgbọ́ mi ró ṣinṣin. É dara pò pèlú mí nínú ìrìn àjò olójó méje níbi tí aó ti fi agbára tí ó wà nínú dídúró ní idakẹrọrọ àti ìrètí fara mọ àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Olórun tí kìí yẹ̀ lái nípa ìlérí rè. Ẹjé kí á gba agbára àti ìtùnú láti inú òrò Olórun.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Omoyemi Ojo fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: mywaitingroom.co.uk









