Wíwá Àlàáfíà Nínú ÌdúróÀpẹrẹ

Wíwá Àlàáfíà Nínú Ìdúró

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ojó Kínní: Ohun tí mo ní ìfé sí

“Gbó Olúwa nígbàtí mo bá fí ohun mí pé; sàánú fún mí pẹ̀lú kí ọ sì dámi lóhùn. Nígbàtí o wípé e máa wá ojú mí (nínú àdúrà máa wá ìwà láàyè mí gégébí ohun tí onílọ̀ tí ó ga jùlo). Ọkàn mí wí fún o pé, ojú rẹ Olúwa li ẹ̀mí ó máa wá (lórí àṣẹ òrò re)” Orin Dafiidi 27:7-8 (AMP).

Ohun tí a ní ìfé sí máa ń sáábà kún wa lókàn ju ìbáṣepọ̀ wà pèlú Olórun ló, ó jé ohun tí ó máa ń wò wá léwù tí ó sí ńda ìrìn àjò ayé wà rú.

Mo se ìrántí àwọn àsìkò kan nínú ìrìn àjò ayé mí nígbà tí mo ń dúró láti gba ẹ̀sì ìwé ìwásè tí mo kọ, mo lè wà ní ojú òpó ayélukára mí, ókéré tán ní èèméwá ní ojúmọ́, pàá pàá jùlo ní àkókò tí kìí ṣe àsìkò isé ní ìrètí ìyanu ní ògànjó ọ̀ru, kòsí ohun kóhun tí ó kàn mí ní àsìkò yí ju èsì tí ó se kókó sími lo lórí èro ayélukára. Mo ti gbàdúrà sùgbón ọkàn mí kò lélè lórí èsì àbájáde tíó ṣeéṣe kín gba, mọ̀ ń tèè síwájú lórí èrọ̀ ọkàn mí láti ìbéèrè dé òpin tí mo ṣì ń wá àbáyo míràn. Bí mó se ń fí èrọ̀ míràn kún èrò ọkàn mí tó, bé ni àkókò ìdúró mí ńpọ̀si, sùgbón lójijì mo rí wípé mó nilọ̀ láti dẹ́kun àwọn èrò ọkàn mí, kí àwon èrò ọkàn mi má à darí mí, ati wípé èrò ọkàn mí láti ìbéèrè dé òpin ń se àfihàn àìní ìgbàgbọ́ àti òye nínú ìwà láàyè ìṣẹ̀dá Olórun.

Ìfé ọkàn wa sí Krístì gbódò ju èrò ọkàn wa sí ohun tí bá lérò wípé ó wúlò fún wà, kí a baà le rí àwọn ohun tí ó wúlò ní tòótó fún wa gbà. Nínú òrò Olórun, Olórun ń bi wá láti máa pọ̀nùngbe fún òun ju bí a tí ń pọ̀nùngbe fún àwọn ohun tí ó lẹ fún wa lọ. Ó fé kí á máa wá ìwà láàyè òun ju wíwá ẹ̀bùn òun lo. Mo ti kó èkó láì mò iye ìgbà wípé Olórun ńlo àsìkò ìdúró wa láti ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú àfojúsùn àti ohun tí a ní ìfé sí, láti rànwálówó ká lè tún èrò inú wa pa ní yíyan àwọn oun to se pàtàkì sí wà.

Ní báyìí, jé olótìtó sí ara re, kíni àwọn ìfé ọkàn re tí ó jùlọ lásìkò yìí.

Ero Inú: Ǹjé ọ sì ní ìfé àti ìgbàgbọ́ nínú Olórun, tí kò bá fún o ní awọn ìfé ọkàn re.

Nípa Ìpèsè yìí

Wíwá Àlàáfíà Nínú Ìdúró

Ní ìgbà kan tàbí òmíràn, gbogbo ènìyàn gbódò ní ifòrítì ní àsìkò ìdúró. Ní ìgbà àti àsìkò tí mo wà nínú ìdúró,mo se àwárí agbára tí ó wà nínú òrò Olórun àti àwọn ẹrí ti ó runi sókè láti ẹnu àwọn ènìyàn kan láti gbé ìgbàgbọ́ mi ró ṣinṣin. É dara pò pèlú mí nínú ìrìn àjò olójó méje níbi tí aó ti fi agbára tí ó wà nínú dídúró ní idakẹrọrọ àti ìrètí fara mọ àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Olórun tí kìí yẹ̀ lái nípa ìlérí rè. Ẹjé kí á gba agbára àti ìtùnú láti inú òrò Olórun.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Omoyemi Ojo fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: mywaitingroom.co.uk