Wíwá Àlàáfíà Nínú ÌdúróÀpẹrẹ

Wíwá Àlàáfíà Nínú Ìdúró

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ojó Kẹrin: Ìjérì Adétútù

Láti inú ìrora ọkàn sí isé ìyanu wa títí láì:

A ṣe ìgbéyàwó ní oṣù kewàá ọdún 2021, sí ògo Olórun ní ìgbà tí yòó fi di oṣù kẹta ọdún 2022, aṣẹ àkíyèsí wípé ati ní oyún. Inú wa sí dùn gidigidi. Ní ọ̀sẹ̀ kejìlá gégébí àgbékalẹ̀ àyèwò tí a ṣe ní ilé ìwòsàn a ríi wípé oyún náà ti bàjé pátápátá. A sọkún, ohun gbogbo sí dojú rú sùgbón atètẹ̀ yí padà sí inú àdúrà láti bèèrè fún agbára àti ìtùnú láti òdò Olórun àti láti òdò olùsóàgùntàn. Látàrí gbogbo ìrora wa síbè ìrètí ńbe láàyè nínú ọkàn wa. A pinnu láti dúró kí á sì padà bò sí ipò, sùgbón padà lóyún ìmíràn ní àsìkò tí Olórun tí pin nu, sàtánì mú’fo. Nígbàtí ọ dí ọ̀sẹ̀ kẹfà àyẹ̀wò ilé ìwòsàn tí a ṣe sọ wípé ohun gbogbo ní ọ wà bí ó ti yẹ, sùgbón nígbàtí ó tún di ọ̀sẹ̀ kejìlá, a tun pàdánù oyún eléẹ̀kejì. Ohun gbogbo dojúrú ní àsìkò yí ju ohun tí a lérò lo, nítorí wípé aọ̀ lérò láti la irú àsìkò yí kọjá rárá, a kò tiè palẹ̀mó dee irú ìrírí yìí nínúu ìgbéyàwó rárá. Àwọn Àsìkò yí kò rọrùn rárá sùgbón á dìrò mọ́ ìlérí tí ó wà nínú ìwé jeremíàh 29:11 ní ìgbàgbọ́ pé Olórun ní ojó iwájú àti ìrètí fún wa.

Léyìn ìrírí kíní àti ìkejì a lérò wípé ogún tí sé, a gba ilé ìwòsàn lo láti ṣe àyẹ̀wò fínífíní wón sì sọ pé oun gbogbo wà bí ó tí yẹ. Léyìn èyí, oyún kẹta tún bàjé bákannáà, ìbànújẹ yí pò tó béè gé, ìdààmú wá pọ̀si síbè adúró ṣinṣin nínú ìlérí Olórun nípa àdúrà gbígbà ti a sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìyanu rẹ̀.

Nínú gbogbo ìrora wọ̀nyí ojú rere Olórun dájú síbè, kìí ṣe ènìyàn tí yíò fi ṣèké, a sì gba òdodo rè gbó. Báyìí ni oyún eléẹ̀kerin tún dé, á gbàá pèlú ìrètí, ala ọ̀sẹ̀ méjìlá kọjá bíi eré bíi awàdà, Olórun mú wàá làá kọjá, isé ìyanu wa sí dé.

Lónìí a jérìí isé ìyanu Olórun, àdúrà wá ti gbà, kìí ṣe ní pa agbára wà, sùgbón nípa oore ọ̀fẹ́ Olórun ni. Ọ bá wa sòrò láti ẹnu àwọn ènìyàn, olùṣó àgùntàn, òré, òrò rè sì dì wá mú títí dé ìmúse ògo rè nínú ayé wa.

Máṣe dékun gbígbà gbó, máṣe dékun dídúró dé oluwa, máṣe wá ìrànlọ́wọ́ àjèjì lo, jékí Olórun jé ohun gbogbo fún ọ. Tí ó bá ṣeé fún àwa, yíò sì tún ṣeé fún ìwo náà.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Wíwá Àlàáfíà Nínú Ìdúró

Ní ìgbà kan tàbí òmíràn, gbogbo ènìyàn gbódò ní ifòrítì ní àsìkò ìdúró. Ní ìgbà àti àsìkò tí mo wà nínú ìdúró,mo se àwárí agbára tí ó wà nínú òrò Olórun àti àwọn ẹrí ti ó runi sókè láti ẹnu àwọn ènìyàn kan láti gbé ìgbàgbọ́ mi ró ṣinṣin. É dara pò pèlú mí nínú ìrìn àjò olójó méje níbi tí aó ti fi agbára tí ó wà nínú dídúró ní idakẹrọrọ àti ìrètí fara mọ àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Olórun tí kìí yẹ̀ lái nípa ìlérí rè. Ẹjé kí á gba agbára àti ìtùnú láti inú òrò Olórun.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Omoyemi Ojo fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: mywaitingroom.co.uk