Wíwá Àlàáfíà Nínú ÌdúróÀpẹrẹ

Ojó Kejì: Ìdúró Rẹ
“Mósè sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, e má bẹrù, é dúró jé kí e sì rí ìgbàlà Olúwa tí yíò fi hàn yín lí òní, nítorí àwọn ará égíptì tí èyín rí lónìí, èyin kì yíò tún rí won mó láíláí. Nítorí tí Olúwa yíò jà fún yín kí èyin kí ó sì pa enu yín mó” Eksodu 14: 13 -14(NLT).
Èyí ní ọ̀kan nínú esè bíbélì tí mo ní ìfésí jùlo, nítorí pé ó máa ń ránni létí pé Olórun yíò jà fún o tí ọ bá gbàá láàyè láti ṣe béè. Gégébí ènìyàn á ní ìfé láti máa darí ó sì máa ńsọ̀rọ fún wà láti dúró jé kí a sì màa wòye. Bákan náà a máa ń ro pé fífi ọkàn wa sí òrò ayé wa yóò mú àṣeyọrí wá. A rí gégébí oun tí ó rọrùn fún wa láti jérìí gbe ara wa ju ẹlòmíràn lọ.
Ju gbogbo rè lo, ejékí áran ara wa létí òrò ìfọ̀kànbalè yìí, ogun náà kìí ṣe tìre, sùgbón ti Olórun ní. Olórun ní ìfé sí ó sì ńdókówọ̀ lórí ayọ̀ àti àṣeyọrí wa ju bíi tiwa lo. Asèdá máa ń wá àṣeyọrí ohun tí ó dá. Kòsí olùdásílẹ̀ tí yíò fé kí ohun tí òun ńṣe bàjé
Bíbélì sọfún wa wípé kí á kó gbogbo àníyàn wa lé Jésù, nítorí ọ fé láti tójú wa. Mathieu 6:26 so wípé, bí baba yín tí nbe ní òrun bálè pèsè fún ẹyẹ ojú òrun, èyin kò ha sàn jù wón lo. Esè 27 wa béèrè ìbéèrè ńlá kan wípé “Ǹjé enikéni nínú yín níní làálàá yín fi wákàtí kún ojó orí rè”. Ejékí á dààmú ní ìwòn, ní àsìkò ìdúró wa. Esè Bíbélì wa tí òní nkó wa wípé kí á má bèrù. Àṣẹ tí ó ga jùlo nínú bíbélì ní èyí, síbè ó rọrùn láti kùnà. Nígbàtí èrò ọkàn re bá bèrè sí pọ̀ruru, tí èrù àwọn ohun àìmò kún ọkàn rẹ, ọ nílọ̀ láti fi òrò Olórun borí èrò ọkàn rẹ. Máa rán ara re létí wípé kìí ṣe ènìyàn sùgbón Olórun ni oń jàà fún ọ. Òun ni oń darí ètò ayé rẹ, tí ó sí jékí kádàrá ènìyàn dájú wípé ohun gbogbo ńsisé pò fún rere fún àwọn tí ó jé tirè. Èyí náà ni Olórun kannáà tí ó dá òrun òhun ayé, tí ó sì ṣẹ ètò ìràwọ̀, òṣùpá àti òòrùn. Tí ó sí mú kí ohun gbogbo kí ó wà ní ètò, kí ayé kí ó má bàá dáwó dúró fún ara rè. Òhun náà ni Olórun kannáà tí ó ń jàà fún ọ.
Ọ̀ré mí ọ̀wọ́n, dúró jé kí ọ sì ní sùúrù, lóòtó dídúró rọrùn ní sísọ ju síse lo ní òpò ìgbà, sùgbón ohun kan tí mo kó ni láti máa tún òrò Olórun kà lórí èrọ̀ ọkàn mí, kí n gbé ohùn mi sókè, kín sì mú èrò òdì ọkàn mí kúrò. Títí di ìgbà tí ìdúró mi, sùúrù mi àti àlàáfíà mi yíò di gbígbà padà.
Ìgbésẹ è Gbígbé: Lọ àwọn òrò Olórun wọ̀nyí, máa kà ní àìmọye ìgbà, Títí ọ fi dé ìpele Ìdúró àti àlàáfíà
Nípa Ìpèsè yìí

Ní ìgbà kan tàbí òmíràn, gbogbo ènìyàn gbódò ní ifòrítì ní àsìkò ìdúró. Ní ìgbà àti àsìkò tí mo wà nínú ìdúró,mo se àwárí agbára tí ó wà nínú òrò Olórun àti àwọn ẹrí ti ó runi sókè láti ẹnu àwọn ènìyàn kan láti gbé ìgbàgbọ́ mi ró ṣinṣin. É dara pò pèlú mí nínú ìrìn àjò olójó méje níbi tí aó ti fi agbára tí ó wà nínú dídúró ní idakẹrọrọ àti ìrètí fara mọ àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Olórun tí kìí yẹ̀ lái nípa ìlérí rè. Ẹjé kí á gba agbára àti ìtùnú láti inú òrò Olórun.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Omoyemi Ojo fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: mywaitingroom.co.uk