Wíwá Àlàáfíà Nínú ÌdúróÀpẹrẹ

Wíwá Àlàáfíà Nínú Ìdúró

Ọjọ́ 3 nínú 7

Ojó Kẹta: Ìdáhùn rè

A máa rọrùn láti gbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn nígbàtí a bá fé gba ohun kan lówó Olórun. Ó rọrùn gan-an ni láti gbàgbé àwọn ẹlòmíràn nínú ìṣòro tàbí àṣeyọrí wọn. Báwo ní ọ ṣe máa ń dáhùn sí pípín ayọ̀ àwọn ẹlòmíràn pẹlú rẹ, pàápàá jùlo tíó bá jé irú ǹkan tí ó n'retí. Fún àpeere, nígbàtí ọ̀ré rẹ bá rí ọkọ àfésónà, tí àwọn ọkùnrin tí ó sí wà ní àyíká rẹ kò da enu ìfé ko é, báwo ni ọ ṣe dáhùn. Tí mo bá ń béèrè ìdáhùn rẹ, mó ń sọ nípa èrò ọkàn rẹ kìí sí ṣe òrò ẹnu rẹ. Báwo ni ọkàn rẹ ṣe ń dáhùn nítorí Olórun rí ọkàn rẹ. Sé óń dáhùn pèlú ìkorò ọkàn tàbí òwú jíje?

Óse pàtàkì láti máa yọ̀ pèlú àwọn ẹlòmíràn ní ìgbà tí ènìyàn bá wà ní àsìkò ìdúró, kí á sì máa pín pèlú ìrora àti ẹrù wúwo awon tí ń la ìṣòro kọjá. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà a máa ń gbójú kúrò lára ìrora àwọn ẹlòmíràn nítorí alérọ̀ wípé ìṣòro tiwa náà pò ju tiwon lọ. Lóòtó oun tí ìwo ńlà kọjá l'ejé kíńkin ní nínú ìṣòro tiwọn. Léẹ̀kan sí, báwo ni ọkàn rẹ ńṣe ń dáhùn sí ìṣòro àwọn ẹlòmíràn, sé ọ̀ń káànú wọn tókàn tókàn, tàbí ọ̀ń ṣe ìrànlọ́wọ́ àti àdúrótì fún wọn, àbí ón lúwẹ̀ nínú ìkáànú ti ara ẹni?

Ìwé Àwọn Ọba Kejì 4: 8-17 ṣe àfihàn ìtàn obìrin súnémù, enití ìtójú àti ìfifúnni rè sí wòlíì Elisha mú ìdáhùn àdúrà wá bá. Lóòtó ni ó ṣe aláìní sùgbón kó jé kí ìlàkọjá rè bóọ̀ lójú, ó rí anfààní láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ọ sì tètè gbàá mú. Wòlíì Elisha wo èmí ìfifúnni rè ósì wù láti sań fun gégébí isé ré àti láti sọ télè sí ipò àìní rè. Lóòtó ọkọ arábìnrin yìí ti di ogbó tí wọn kòsì ní ọmọ kankan, sùgbón ọ bí ọmọ láàrin ọdún ìsọtélè náà.

Ní òpò ìgbà, ònà àbáyo dé òdò olùrànlówó àyànmó rẹ ńbe níní ìfifúnni re. Máṣe jékí ìfé ọkàn rẹ kí ó ru bọ̀ ó lójú ju láti jé ìdáhùn sí àdúrà ẹlòmíràn. Olórun fi wá ti ara wa, ìrànwọ́ tí ọ bá sì ṣẹ fún ẹlòmíràn lẹ̀ jẹ́ kókóró sí ìdáhùn àdúrà rẹ.

Àròjinlẹ̀:

Tani olè kí kú orí irẹ lónì?

Tani olè gba àdúrà pèlú lónìí?

Tani olè ràn lọwọ lónì?

Nípa Ìpèsè yìí

Wíwá Àlàáfíà Nínú Ìdúró

Ní ìgbà kan tàbí òmíràn, gbogbo ènìyàn gbódò ní ifòrítì ní àsìkò ìdúró. Ní ìgbà àti àsìkò tí mo wà nínú ìdúró,mo se àwárí agbára tí ó wà nínú òrò Olórun àti àwọn ẹrí ti ó runi sókè láti ẹnu àwọn ènìyàn kan láti gbé ìgbàgbọ́ mi ró ṣinṣin. É dara pò pèlú mí nínú ìrìn àjò olójó méje níbi tí aó ti fi agbára tí ó wà nínú dídúró ní idakẹrọrọ àti ìrètí fara mọ àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Olórun tí kìí yẹ̀ lái nípa ìlérí rè. Ẹjé kí á gba agbára àti ìtùnú láti inú òrò Olórun.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Omoyemi Ojo fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: mywaitingroom.co.uk