Ara ÈkéÀpẹrẹ

Ara Èké

Ọjọ́ 7 nínú 7

Ríronú nípa akitiyan tí a ń ṣe láti fi àwòrán tó pé hàn ń yani lẹ́nu ká má sọ míì. Kódà lẹ́yìn taa bá ti lo gbogbo ayinike ètò ìdàgbàsókè ara tán, a ṣí máa wò jingi lópin ọjọ́ taa sì tún máa rò ó wípé, “Ǹjẹ́ mo tíì tó, síbẹ̀síbẹ̀?”

Àmọ́ ó, òtítọ́ yí rọrùn púpọ̀ láti gbà nígbàtí a bá ríi wípé gbogbo akitiyan wá kí ṣe asán nìkan, sùgbọ́n wọn kò wúlò rárá. Kódà kí a tó bí ọ, ní o ti ní ìdánimọ̀ tí kò lè yẹ̀: ìfẹ́ aláìníìdí ni Ọlọ́run fi fẹ́ ọ. A dá ọ ní àwòrán Ọlọ́run.

Tí a bá lérò láti mọ ara wa ní òtítọ́, a ní láti dojúkọ òótọ́ ọ̀rọ̀. A wà lójú ogun pelu ota gidi, ó sì fẹ́ fà àlà púpọ̀ s’áàrin àwa ati òtítọ́ Ọlọ́run.

Gbogbo irọ́ tí a gbàgbọ́ tó sọ pé a gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ láti j’ogún ìfẹ́ Ọlọ́run a ma fi agbára fún ara èké wá. Àwọn irọ́ wọ̀nyí á máa díwa lójú láti rí èni ti a jẹ nínú àwòrán Ọlọ́run.

Àsìkò tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe iyèméjì nípa ìfẹ́ aláìníìdí rẹ̀ fún wa ní àkókò tí a bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣubú. Kò sí àkókò kan tí ọ̀tá sọ fún Ádámù àti Éfà kí wọn jẹ èso…., irọ́ ló gbìn. Ọ̀tá ó kii ṣe onidanwo ìwà ìbàjẹ́; bàbá irọ́ ló jẹ́.

Síbẹ̀ kódà nígbàtí a bá gba àwọn irọ́ náà gbọ́ tí a sì pàdánù ojú àmì, à ń lépa wa pẹ̀lú ìfẹ́ tí kìí jáwọ́, tí ó sì ṣe onírẹ̀lẹ̀. Rírí kọjá ìbòjú wa, Ọlọ́run rí wa gẹ́gẹ́ bíi àwọn ọmọ tó sọnù láìsí oun. Ọlọ́run, Bàbá Rere, n ja fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.

Ẹni tí ìwọ jẹ́ nìyí - àyànfẹ́ Rẹ̀. Ìwọ ó kùnà - a rí ọ nínú ìfẹ́ pípé Ọlọ́run. Ìdánímọ̀ rẹ ó kìí ṣe kàyéfì - a dá ọ ní àwòrán Ẹlẹ́dàá àti Ọba ayé.

Ìríṣí:

Njẹ́ ó ṣe tán láti bọ́ ìbòjú rẹ, ké pe Ọlọ́run, kí ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò gbígbé ayé gẹ́gẹ́ bíi ẹni òtítọ́ rẹ.

Àdúrà:

Ọlọ́run, mo mọ̀ wípé ó nífẹ̀ẹ́ mi. Yí ọkàn mi padà kí ó sì tún ẹ̀mí mí ṣe bí mo ṣe ń wá láti mọ ẹni tí mo jẹ́ nínú rẹ. Amin

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Ara Èké

Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com